Anígunmẹ́ta
Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Anigunmeta (triangle) je okan ninu ipilese irisi aniwonile: anigunpupo (polygon) pelu elenusonso (vertex) meta ati egbe meta ti won apa ila (line segment) gbooro. Irisi yi lo mu eka imo isiro ti a mo si Iwon anigunmeta (trigonometry) wa. Eyi fihan wa bi o se se pataki to.
[s'àtúnṣe] Orisirisi awon anigunmeta
A le se eka anigunmeta gege bi ibu awon egbe won se to:
- Anigunmeta onibukanna (equilateral triangle): gbogbo egbe meteta ni won ni ibu kanna.
- Anigunmeta onibumeji (isosceles triangle) : egbe meji nikan ni won ni ibu kanna.
- Anigunmeta onibumeta (scalene triangle) : ibu otooto ni egbe meteta ni.
Oníbùúkaánnà | Oníbùúméjì | Oníbùúmẹ́ta |
A tun le se eka awon anigunmeta gege bi itobisi awon igun inu won se to:
- Anigunmeta onigunrege (right-angled triangle): o ni igun kan to je 90° (Aadorun iyi)
- Anigunmeta onigunsonso (acute triangle): igun meteta inu re kere ju 90° lo.
- Anigunmeta onigunfenfe (obtuse triangle) : o ni igun kan ti o tobi ju 90° lo.
Onígunrégé | Onígunfẹ̀nfẹ̀ | Onígunsonso |