Buddhism
Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́
BUDDHISM (ÈSÌN BUDDA)
ÌBÍ BUDDA
Ìgbàgbó ìbílè fi han wí pé a bi Budda si ìdílé Oba ni Orílé-èdè “Lumbini, Nepal ní Teria” leba “Himalayas”. Nítorí náà, àwon àwòràwò wí pé ní ìlú “Kalinga” èyí tí o ti di òrìsà àkúnlèbo ní ìlú “India” ni a gbé bí i.
O jé omo ebí “Sakays”. Orùko bàbá re ni “Suddhodana”. A bí Budda nínú ìdílé Oba. Orúko ìyá re ni “Maya”.
Kò si eni ti o mo àkosílè ojó ibi rè pàtó tàbí ti o ni àkosílè rè. Olúkúlùkù kan nso àwon ojó ti won rò pe o le jé ni nítorí kò si àkosílè kan pàtó ti a le toka sí. Àwon onpìtàn kan ní a bi i ni odun “623 tàbí 624 BCE”. Kò pé kò jiìnà yíì ni àwon elésìn kan so wí pé ojo ibii rè títí di ojó ti o gbé lórí eèpè jé ni aarin odún 567 si 487 BCE” .
Òpòlopò àwon òjògbón wí pé a bí ì ni Odún 420 sí 502 BCE” ki a ma fi òpá pòlòpolo pa ejò, kò sí ìdánilójú ojó ibii rè àti ojó ti ó lò láyé.
Àwon ohun ti a ri nínú àkosílè ti o se pàtàkì ni pé a bi i ni ònà ìyanu. Léhìn ìbí rè, o dìde dúró ó gbé àwon ìgbésè nínú èyí tí o kede ara rè wí pé òun yoo jé ìjòyè ayé. O wí pé èyí ni yoo jé ìgbà ti òun yoo padà wá sáyé gbèhìn.
Orúko ti àwon obi ré so o ni “Siddhartha Gautama”. “Siddhartha” . Eyi túmò sí “eni ti o ti kése járí sùgbón “Gautama” ni orúko ìdílé tí a bí i si. Òpòlopò ìgbà ni won má n pe e ni “Sakayamuni”, itumò èyí tí n jé amòye nínú “Sakyas”.
ÌBÈRÈ PÈPÈ AYÉ RÈ
“Sakyamuni” jé eni ti a tó lónà èsìn “Hindu”, èrò àwon òbí rè ni ki o jé arópò Bàbá rè léhìn ìgbà tí ó bá gbésè. Wón ro wí pé yoo lánfààní lati jé ìlù moóká Oba tàbí olórí èsìn nlá kan ti o se jìnmòwò. Àwon òbí rè tóo ni ona olá àti olà kí ohun ti o wá se l’áyé lé rorùn fún-un àti ki o le gbé ìgbé ayé èsìn won.
Ní ìgbà tí o di omo odún mérìndínlógún ni o gbé ìyàwó, orúkó ìyàwó rè a má jé “Yasodhara”, Nígbà tí o pé omo odún mókàndínlógbón ni ìyàwó rè bi omo okùnrin kan fún-un orúko rè a ma jé “Rahula”. Léhìn tí o bi omo yii tán ìtàn fi ye wa wí pé o se ìrìnàjò lori èsìn léèmérin òtòòtò, nígbà tí òpò ìtàn so wí pé n se ni o ri ìran léèmérin. Nínú ìrìnàjò rè àkókó o ri okùnrin arúgbó kan ti o jé aláilòlùránlòwó, ní ìrìnàjò re kejì ó rí okùnrín ti àìsàn ti o lágbára juu lo n ba a fínra, ní ìrìn àjò re keta o ri ìdílé kan ti ìbànújé bò mólè ti won si ngbé okàn nínú won ti o se aláìsí lo si ibojì. Ó ronú jinlè lórí ìsòro ti àwon arúgbó n kójú bi àìsàn àti ikú.
Nínu ìrìn àjò rè kerin, o ri elésìn kan ti o pè sí ìrònú nípa ohun ti o rí nígbà yii ni òkan re to rú sókè láti tèlé ònà àti le se ìrànlówó nípa ti èmí papa fún ìsòro ti o n kojú omo ènìyàn.
Ó fi aya, omo àti ìgbé ayé ìròrùn àti ìgbá ayé asáajú àwon ènìyàn rè sílè lati se ìwadi ìyànjú ìsòro èdá.
Ní àkókò nàá àwon okùnrin miran a ma kúrò ni ilé lati lo d’ánìkàn wà nínú igbó tàbí ibití o se kólófín nítorí won fé mo àwon ohun ìjìnlè kan.
WÍWÁ ÒNÀ SI ÌSÒRO TI O N KO ÈDÁ LÓJÚ
O kókó gbìyànjú lati ronú ohun tí o kó lati òdò àwon olùkó re méjì òtóotó, o rò wí pé èyí ni ó se iyebíye.
Sùgbón ìrònú yii kò le tèsíwájú lo títí nítorí náà o yípadà nínú ìrònú náà ki o le dojú ko àwon ìsoro náà tí ó n fé yanjú èyí, ti o jemó ìbímo, àìsàn ojó ogbó àti ikú.
Ó dara pò mó egbé ti won jo ni èrò kan lorí wíwà ònà si ìsòro tí o n dojúko ènìyàn, ní béè ni o ti ko onírúrú ohun bi ki a sé èémi àti bi a ti gba àwè léraléra.
Àwon ohun ti o gbékalè fún ara re yìí jé ohun ti o nira lópòlopò nítorí náà o fi sílè lai tún tèsíwájú nípa re mó, àwon ti o se fífi íyá je ara eni gbíga àwè tàbi sìn rè “Hendu” kò si ònà àbáyo si ìsòro ti o nfé ìyanjú nítorí náà o tún pinnu láti se àwárí ònà míràn láti le tú àwon ènìyàn sílè nínú ìsòro ti o n dojú ko wón.
ÀWON ÌFOYÈHÀN BUDDA
Ni àsálé ojó kan ni “535 BCE” ni ìgbà tí o pé omo odún márùndínlógòji O joko lábé igi nla kan ti a mò si igi Bódì. O bèrè si ni ri ìrírí nípa àseyorí t’èmí.
(1) Ní alé àkókó o rántí ìgbé ayé kí a kú ni ibikan ki a si tún wà ni ibòmíràn gégé bi alààyè.
(2) Ni ale oji keji o ri bi igbe aye ibi ati ika ti opolopò ma n gbe se ma n so ibiti won yóò lo lehin iku.
(3) Ni alé ojo keta o kó wí pé oun ti tèsíwájú koja ipele biba emi jé nipa ikorira, ibinu, ongbe, iberu àti ijaya o si pinnu wí pé oun ko tún ni wá s’áyé mó. O ti ni ifoyehan o si di “Olugbala, enito n gbani àti Olùràpadà”
Léhìn ìfoyèhàn rè yi o gbìyànjú láti jé ki òpò ènìyàn mò nípa pipolongo èkó rè si wón èyí ti òpòlopò si gbàgbó ti won si n tele èkó rè.