Theatre
Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Tíátà
Tíátà jé òrò tí ó wáyé lati inú èdè Gíríikì tí o túmò sí ibì ìwòran ó sì tún ní èka bí eré ìtàgé tí ó túnmò sí pé, nígbàtí ènìyàn kan tàbí jù béè bá kó ara won jo ní àkókò kan tábì sí ìbìkan láti dá àwon ènìyàn lárayá. Nípa ìtúmò tí ó gbòòrò yí, lati ìgbà tí ènìyàn ti wà láyé ni tíátà ti wà to béè ge ti ó se sajejuwe ìgbé ayé ènìyàn nítorí Ìfé àwon ènìyàn si ìtàn síso. Lati ipinlèsè tíátà, ni ó ti n mú orísiirísi àrà dání. A sì máa n ló àwon èròjà bi òrò, ìsesí, orin, ijó àti ìwòran papò mó eré ìtàgé sínú tíátà. Tíátà ayé ìsinsìnyí ni ó tún kún fún òtíto bí ó tilé jé pé ó pín sí orísiirísi ònà.
Tíátà àkókó ní a se ní ègberún odún méjì sájú ikú Olúwa wa séyìn, ni ó jé eré ìtara nípa ilè Ígíbítì ìgbanì. Ìtàn nípa Olórun órísírì ni wón fi n se tíátà ni ododún lati sin Olórun ósírísì won yi títi di ìgbà yé òlàjú, èyí wá fi hàn nípa ìbásepò tí ó wa láàrín tíátà àti èsin.
Àwon ará Gíríkì ìgbanì ni ó kókó se àgbékalè tíátà gégé bí ìse, wón sì túnmò tíátà sí orísirí ònà bí eré ti adùn kéyìn rè, eré ti ìbànújé kéyìn rè àti eré tí ó se àpèjúwe àwùjo.
Sùgbón láyé òde òní, tíátà síse ti gba ìgbà òtun, tí à n se sínú fánrán fún àgbéléwò àwon ènìyàn fún ìgbádùn. Tíátà síse ti wá da isé òòjó àwon kan lóde òní. Tíátà àsà àti ise tí àwon òsèrè máa n lò latí se ìgbélékè àsà àti ìse tí ó ti dòkú, pàápàá ní ilè Áfíríkà. Nípa tíátà ni a ti mò pàápàá ni ilè Yorùbá àwon àsà ati ise wa, tí ó ti sonù nítorí àsà àti ìwà àwon òyìnbó ti gba àsà àti ìse wa lówó wa.
Òkan nínú ìsòrí tíátà ni, tíátà nípa àwùjo àti òsèlú. Tíátà nípa àwùjo nì àwon eléré ìtàgé fi n se òpòlópò àyípadà sí àwon àlébù àti kùdìè-kudie tó kù nínú àwùjo wa lónìí. Nípà tíátà síse yálà nípa eré ìtàgé tàbí ti àgbéléwò ni àtúnse ti n bá òpòlopò ayé tí ó wà ní ìkòríta ìríjú, tí won kó si mo ohun tó ye lati se. Òpòlopò olósèlú ni bá tí so ayé di tàwon nìkan, bí kò bá sí ti àwon aléré ìtàgé tábì ti àgbéléwò tí óun pi ìwà ìbàjé won léde.
Tíátà tí ó ti wà lati bí òpò odún séyìn, ló ti gbá àtúnse nípa ìdàgbàsókè tí ó ti dé báa ní ayé òde òní. Tíátà sise yálà ti eré ìtàgé tàbí ti àgbéléwò ló wà fún èkó, ìtósónà ati fún ìsàtúnse àwùjo tí a wà lónìí.