Jainism
Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(JANISM) JANISIIMU
Ìtàn bí èsìn Jánísímù se bèère
A leè topasè ìtàn yìí lo si ìlú Indíà. Jánísímù ítumò èyí tí o jé àwon ti o ségun. Eni àkókó nínú ìsìn yíì jé elèsìn ìbílè kan tí ó jinlè enití ó ti wá s’áyé níwòn nkàn bi òpòlopò odún s’éyìn enití o tún jé omo léhìn rè gbèhìn ni “Vardhamana” (a.k.a Mahavira). Akoni èdá enití à bí ni 550 BCE òun sì ni olùpilè èkó tàbí èsìn Jánísímù ní odún 420 BCE ni o gb’èmí ara rè nípa ìwà ti a mò si “Salekhama” eyí tíi se àwè gbígbà títí di ojú ikú, àwon ti o n tele e gbà wí pé àwon ti ségun ìbínú, ikorira, ìfé àti adùn ti won si ti so okàn dòmìnira.
ÌGBÀGBÓ ÀTI ÌSE ÀWON ELÈSÌN JÁNÍSÍMÙ
1. Wón gbàgbó wí pé ayé wà ó sì ní orisirisi ibùdó béè ni kò ni ìbèrè àti òpin
2. Ipele ti o tayo: A le rí eleyi lókè pàtàpàtà ayé níbití okàn tí à ti dá nídè ngbé.
3. Ipele tí o ga l’áyé: Won gbàgbó wí pé òrun ogbòn níbití àwon mímó ngbé
4. Ìgbàgbó won ní pe ayé kan nbee láàrin
5. Won ni ìgbàgbó nínú ibùgbé kan ti a n pè ni “Nigoda” ní ibití àwon ènìyàn ngbé
6. Ojú òfúrufú àgbáyé tí o ni Onírúrú àwosánmò tí ó yíka
7. Ìyàtò wà láàrin gbogbo ènìyàn nípa ìwà ti a n wù rere tàbi ìwà ibí
8. Òmìnira kúrò nínú ayé nípasè ìwàláàyè ní ibòmíràn.
9. Won tún gbàgbó pé kò si èdá kan tí o gbódò wu ìwà ìkà si eranko tàbí sí ewébè tàbí sí ènìyàn.
10. “Asteya” tumò èyí tí se olúsín Jánísímù kò gbodò jalè.
11. Won kò gbodò je enití o n kó orò jo fún ara rè ju ìwòn tí ó nì lò lo
12. “Sakya” Wón gbódò ma so òtító kí won si yàgò fún èké.
13. Kíka ìwé èsìn won jé ohun tí o se pàtàkì lójojúmó
14. Won gbódò la àwon ipa wònyí kojá
(a) Ìgbé ayé omo ilé-ìwé
(b) Wón gbódò ni ìdílé
(d) Ìdílé àti ìgbé ayé gbájumò
ÀWON ÌSÒRÍ MÉJÌ TÍ WON PÍN SÍ
(a) Ãwon tí o ma n rìn ìhòhò
(b) Àwon tí ó n wo aso funfun, wón gbà àwon omo léhìn won láàyè lati wo onírúrú aso.
BÍ ÀWON ELÈSÌN JÁNÍSÍMÙ SE N GBÀÀWÈ
Àwè jé ohun ti o sábà ma n jeyo láàrin won, òkan pàtàkì ni o jé lára òpó ìjosìn won. Àsìkò tí won tún ma n agba ààwè ni àkókò ti won ba rí wí pe won ti se àwon ohun ti kò tó, wón si tún má nlo ààwè láti gbé ara wón dúró. Àwon mííràn nínú won ma n ni ìsìn ààwè pàtàkì ti won bá ri wí pé ojó ikú súnmó etílé nítorí náà wón o ni je béè ni won o ni mu ohunkóhun títí di ojó ikú. Irú ikú bayi ni won npè ni “Santhara”
ÈTÒ EBO SÍSE ÀTI BÍ WON TI N JÓSÌN
Ní ojoojúmó ni àwon olùsìn nforí balè lati gba àdúrà won ti won si ma nkó orin si ère ti won gbé kalè eleyi ti o n se àpeere láàrin won.
Lótíitó ni èsìn Jánísìmu kó wa bí ó ti ye kí a ma hùwà gégé bí ènìyàn béè lo si kó wa ni àwon ipele ti a gbódò dé láyé, sùgbón àkíyèsí mi gégé bí ènikan ni wí pé ènìyàn jé aláìlera ti o le pinnu ohun kan ni Owuro ki o si yipada ko di àsálé gégé bí ohun ti ènìyàn je ati nítorí àwon ohun ti o yi wa ka ni òpò ìgbà. Èrò tèmi ni wí pé bi a o ba gbé igbé ayé tí wón ko wa nínú èsìn yíì a ni lo agbára èyítí o kojá òye ènìyàn.