Sàngó
Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Sàngó
Yorùbá bò wọ́n ni àjànàkú kojá a morí nnkan fìrí, bí a bá rí erin, káwípe a rí erin ní òrò sàngó jé láàárin àwon òrìsà ilee Yorùbá. Sàngó jé òrìsà takuntakun kan gbòógì láàárín àwon òrìsà tókù ní ilèe Yorùbá. Ó jé orisà tí ìran rè kún fún ìbèrù. Ìrísí, ìṣe àti ìsọ̀rọ̀ rẹ̀ pàápàá kún fún ìbèrù nígbàtí ó wà laaye nítorípé ènìyàn la gbọ́ pé sàngó jẹ́ télè kí ó tó di òrìṣà àrá. Ìtàn so wí pé omo Òrányàn ni sàngó i ṣe àti pé Oya, Òṣun ati Obà jẹ́ ìyàwó rẹ̀.
Ìhùwàsí búburú ati dídá wàhalá ati ìkolura pèlú ìjayé fàmílétè-kí-n-tutó pò lówó sàngó gégé bí Oba tó bẹ́ẹ̀ títí ó fi di òtéyímiká, èyí jásí wí pé tọmọdé tàgbà dìtè mó o. Wón fi ayé ni í lára. Ó sì fi ìlú Òyó sílè nígbèyìn-gbéyín. Ó pokùnso sí ìdí igi àyàn kan lébà ònà nítòsí Òyó nígbàtí Oya: Ìyàwó rẹ̀ kan tókù náà sì di odò.
Ogbón tí àwon ènìyàn sàngó tókù dá láti fi bá àwon òtá rè jà nípa títi iná bolé won àti béèbéè lo ni ó so sàngó di òrìṣà tí wọ́n ń bo títí dòní tí wón sì ńfi enu won túúbá wí pé sàngó kò so: Oba koso.
ÀWON ORÚKO TÍ SÀNGÓ Ń JÉ
Oríṣiríṣi orúko ni a mọ sàngó sí nínú èyí tí gbogbo won sì ní ìtumò tàbí ìdí kan pàtó ti a fi ńpè wọ́n béè. Àwon orúko bíi ìwònyìí:
1. Olúkòso: Ẹnití a mò mọ́ kòso tàbí oba tí ó wolè sí kòso.
2. Arèkújayé:
3. Àjàlájí:
4. Ayílègbe Òrun:
5. Olójú Orógbó: nítorípé orógbó ni obì tirè, òun ni ó sì máa ń ṣàféérí nígbà ayé rè. Orógbó náà sì ni a máa ń lo ní ojúbo sàngó títí di òní.
6. Èbìtì-àlàpà-peku-tiyètiyè: Òrìṣà tí ó máa ń fi ìbínú gbígbóná pa ènìyàn ni àpalàyà tàbí àpafòn.
7. Onibon òrun: gégé bí òrìsà ó ń mú kí àrá sán wá láti ojú òrun pèlú ìrókèkè tó lágbára.
8. Jàkúta: gégé bí òrìṣà tí ń fi òkúta jà (edùn àrá). Irúfẹ́ òkúta kékeré kan tí ó máa sekúpa ènìyàn nípasẹ̀ sàngó
9. Abotumo-bí-owú: Òrìsà léè wolé pa ènìyàn bi eni pé erù ń lá ni ó wólu irú eni bẹ́ẹ̀.
10. Èbìtì-káwó-pònyìn-soro: Irúfẹ́ Òrìṣà tí ó jẹ́ wí pé ìṣowó-sekúpa asebi rẹ̀ máa ńya ènìyàn lénu gidigidi.
11. Alágbára-inú-aféfé: Òrìsà tí ó jé wípé owọ́jà a re, máa ńwá láti inú aféfé tàbí òfurufú ni.
12. Abánjà-májẹ̀bi: òrìṣà tíí jà láì ṣègbè léyìn aṣebi tàbí ṣe àṣìmú elòmíràn fún oníṣé ibi.
13. Lánníkú-oko-oya: Òrìsà tí o ni èrù iku níkàwó.
14. Òkokonkò èbìtì: Òrìsà tí ó le subú lu ènìyàn bii ìgànnán tí ó ti denukọlè.
15. Eléèmò: Òrìsà tí ó ni èèmò.
AWON IWE ITOKASI
1. Daramola Olu [1967] Awon Asa ati Orisa Ile Yoruba. Lati owo Olu Daramola ati jeje Adebayo
2. Adeoye C. L. [1985] Igbagbo ati Esin Yorùbá. Ibadan. Evans Brother. Press