Obáfẹ́mi Awólọ́wọ̀
Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Obafemi Awolowo | |
Premier of Western Nigeria
|
|
---|---|
In office 1 October, 1959 – 1 October, 1960 |
|
Succeeded by | Samuel Akintola |
|
|
Ojoibi | 9 March, 1909 Ikenne, Ipinle Ogun |
Ojoalaisi | 9 May, 1987 Ikenne |
Egbe oloselu | Action Group |
Profession | Lawyer |
Ẹ̀sìn | Kiristiani |
Olóògbé Obáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ (1909 - 1987), olósèlú, ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lati ẹ̀yà Yorùbá. Awólọ̀wọ̀ jẹ́ olórí fún àwon omo ilé Yorùbá àti òkan nínú àwon olósèlú pàtàkì ni orílè èdè Nàìjíríà. A bí ni ojó kefà osù keta ọdún 1909 ni Ikénne ni ìpínlè Ogun. Omo àgbé tí ó fi isé àti ogun isé so ara rè di omòwe , Awólówó ló ilé èkó Anglican àti Methodìst ni Ikénne àti ni Baptist Boys' High School ni Abéòkúta. Lèyìn rè ó ló sí Wesley College ni Ibàdàn tí ó fi ìgbà kan jé olùìlú Agbègbè Iwó Oòrun Orílé èdè Nàìjíríà láti ba di Olùko. Ní ọdún 1934 , ó di olùtajà àti oníròyìn. O se olùdarí àti alákóso Egbé Olùtajà Awon Omo Nàìjíríà (Nigerian Produce Traders Association) àti àkòwé gbogbogbo Egbé Awon Awako Igb'eru Omo Ilè Nàìjíríà (Nigerian Motor Transport Union).
Awólówó tèsíwájú nínú èkó rè, ó sí gbà ìwé erí kékeré ni ọdún 1939, kí ó tó ló láti gbà ìwé erí èkó gíga nínú ìmò owó ni ọdún 1944. Igbà yí nà ló tún jé olóòtú fún ìwé ìròyìn Nigerian Workers (Osisé Omo Ilè Nàìjíríà). Ní ọdún 1940 ó di àkòwé Egbé Odò Awon Omo Ilè Nàìjíríà (Nigerian Youth Movement) èka Ibàdàn, ibi ipò yí ni ó tí s'olori ìtiraka láti se àtúnse Igbìmọ́ Aláse Idámòràn Fún Awon Omo Ibàdàn (Ibàdàn Native Authority Advisory Board) ni ọdún 1942.
Ni ọdún 1944 o lo si ilu Londonu lati ko eko ninu imo ofin be ni o si se idasile Egbe Omo Oduduwa. Leyin igba to pari eko re ni ọdún 1947 o dari pada wale lati wa di agbejoro ati akowe agba fun Omo Egbe Oduduwa. Leyi ọdún meji, Awolowo ati awon asiwaju Yoruba yioku se idasile Egbe Oselu Action Group eyi ti o bori ninu ibo ọdún 1951 ni Agbegbe Iwo Oorun Ile Naijiria. Larin ọdún 1951-54 Awolowo je Alakoso Fun Ise Ijoba ati Ijoba Ibile, o si di Olori Ijoba Agbegbe Iwo Oorun Ile Naijiria ni ọdún 1954 leyin atunko Iwe Igbepapo Ati Ofin (constitution).
Gege bi Olori Ijoba Agbegbe Iwo Oorun Ile Naijiria, Awolowo se idasile eko ofe fun gbogbo odo lati ri pe moko moka gba le ka. Ni igba ti orile ede Naijiria di olominira ni ojo kinni osu kewa ọdún 1960, Awolowo di Olori Alatako Oselu (Opposition Leader) si ijoba Abubakar Tafawa Balewa ati Aare Nnamdi Azikwe ni Ilu Eko. Aiko enu larin ohun ati Samuel Ladoke Akintola to dipo re gege bi Olori Ijoba ni Agbegbe Iwo Oorun ni o fa jagidijagan ti o sele ni ọdún 1962. Ni ọdún yi ni osu kokanla re sini Ijoba Apapo ile Naijiria fi esun kan Awolowo pe o dote lati doju ijoba bole. Leyin igbejo to gba osu mokanla, ile ejo da Awolowo ati awon egbe oselu re mejidinlogbon lebi esun idote, won si ran won lo si atimole fun ọdún mewa. ọdún meta pere ni o lo ni ile ewon ni ilu Calabar ti ijoba ologun Yakubu Gowon si fi sile ni ojo keta osu kejo ọdún 1966. Leyin eyi Awolowo di Alakoso Ijoba Apapo fun Oro Okowo. Ni ọdún 1979 Awolowo se idasile Egbe Oselu Imole.
Obafemi Awolowo se alaisi ni ojo aiku ojo kesan osu karun ọdún 1987 ni ilu Ikenne. Leyin iku Awolowo Ijoba Apapo yi oruko Ile Eko Giga Ile-Ife si Obafemi Awolowo University. Be si aworan Awolowo wa lori owo ogorun naira fun eye gbogbo ohun to se fun idagbasoke ile Yoruba ati orile ede Naijiria lapapo.