Web Analytics Made Easy - Statcounter

See also ebooksgratis.com: no banners, no cookies, totally FREE.

CLASSICISTRANIERI HOME PAGE - YOUTUBE CHANNEL
Privacy Policy Cookie Policy Terms and Conditions
Management - Wikipedia

Management

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́

ISAKOSO (MANAGEMENT)

ISAKOSO (ABOJUTO)

Ìsàkóso tàbí Ìsàbójútó ni sìse ìtójú ohun kan tàbí ilé-isé ni orísirísi ònà. A lè se àbójúto ni ònà tó gbòòrò tàbí ònà kéréjekéréje.

BÍ A TÍ N SE ÌSÀKÓSO


KIKO ÌLÀNÀ SÍLÈ: Kíko ìlànà tí a ò tèlé láti gbé èrò okàn wa jáde tàbí isé tí a fé muse.

SÌSE ÀTÈLÉ OHUN TÍ A KO SÍLÈ:- Gbogbo ohun tí a bá ko sílè tàbí èyí tí a fi inú rò ni kí á maa tèlé ni sísèntèlé.

SÌSE ISÉ ASÁJÚ:- Asájú ni yíò maa darí àwon yókù láti maa tò ó léyìn nínú ètò tàbí ohun kóhun tí wón bá fé se.

KÍKÓ ARA ENI NÍ ÌJÁNU:- Alákoso gbódò ríi dájú pé òfin wà fún àwon ènìyàn rè làti tèlé, èyí yíò mú kí isé lo dédé gégé bí ó ti ye kó rí.

ÌLÀNÀ ÀBÓJÚTÓ:- A lè se akosílè ohun tí yíò selè ní ojó iwájú (lóòní, òsè tínbò, osù tónbò, odún tónbò, odún máàrún-ún sí àkókò yìí) lórí àwon ìgbésè tí a bá fé gbé tàbí ètò tí a bá fé tèlé.

Sìse Àmúlò gbogbo ènìyàn tàbí irínsé tí yíò mú kí isé yorì sí rere. Nípa bí alámojútó àgbà se ún gbà wón ní ìmòràn tàbí reran àwon omo léyìn rè lówó làti mú isé àti ipa ti won ni òkùnkúndùn.

Ònà míràn ní wipe, kí amáa gbé àwon isé tí a kò tíì se yèwò ní ìfègbékègbé pèlú àwon èyí tí a ti se yorí. Eléyìí yíò je kí à mò. Ibi tí isé kù síí.

Alábòjútó gbúdò jé kí àwon alábaa sílé pò rè mo ìdí tí wón fi kó ara won jo, yálà láti ran àwon ènìyàn lówó tàbí láti je èèrè lóri òjà tàbí isé tíwón nbá se.

Isé ti ènìkanànkan yíò se ní alábòjútó yíò pín fún won ní elékajèka. Òsìsé gbódò kára mó isé tí won bá yàn fún won, Nítotí pé alábojútó lè fi ìyà je èyí tí kò bá sìsé fún àpeere ó lè yoo díè kúrò nínú owó osù irú òsìsé béè.

Àwon òfín tàbí ìlànà tí alákoso bá se gbódò jé èyí tí ó seé yí padà nígbà ku gbà. Ó sì gbodò yé àwon òsìsé yékéyéké.

A gbódò gbé ohun èlò tàbí èròjà amúséyá yèwò, kó má ba fà ìdádúró kankan ní ìgbà tóye kí isé máà tèsíwájú.

Alábòjùtó lètó àti pààlà láààrín ise ati eré àti bí wón yóò se lo gbogbo èròjà tó wónní, láti fún ní ìyorísí rere gégé bí won ti se fé láti ìbèèrè pèpè.

MÍNÚ ÒFÍN ÀTI ÌLÀNÀ DÍ OHUN ÀMÚLÒ: Gbogbo alábòjùtó ni elékajèka ni wón gbódò yán òfin àti ìlànà tí wón fé lò ní etí won. Gbogbo won ni yóò so èrò okàn won bí o bá se rí ní ojú tiwon àti ìrúfé ànfàaní tí yíò gbé se ní eká ti won.

Alábòjútó gbódò mò níbo ati ònàwo ní a ó gbà làti fi ìdí òfín àti ìlànà isé mule ní àárin àwon omo léyìn rè. (òsìsé) Isé otòtò ní a gbódò yà sótò fún èka kéréjekéréje ní ilé isé, èyítí yíò fún won ní ìròrùn àti forí isé won lé ònà bí won ti kó sílè ní ìbèèrè.

Òfin àbí ìlànà ilé-isé tàbí ohun tí abá fé se lóye kí a máa gbé yèwò lóòrèkóòrè. Kí a lè máa rántí nígbà gbogbo.

Agbódò ní ètò fún àwon ohun tí a kò rò télè, bí ati lè se yí liana padà tí nkànkan bá selè, eléyìtí kò ní dí isé won lówó.

Àwon ògálògá gbódò máa se àyèwò nígbà gbogbo lórí bí àsèyorí se máa n dé bá ètò ilé-isé náà.

Agbódò wà ní àyíká tó dára láti mú kí órorùn fún àwon òsìsé láti sapá won ní gbogbo ònà. Kí àjínde lè dé bá isé won lápàpò.

Ìdàgbàsókè òfin àti ìlànà isé

Agbódò gbé isé, ìdí tí wón fi wà, agbára àti ibitókùsí fún èka kànkan yè wò láti jé kí wón mo ànfààní tàbí pàtakì isé won nínú ilé-isé.

A gbòdò maa gbèrò télè ohun tí ólè selè ní agbègbè ní ojó iwájú ilé-isé tàbí ohun tí àn gbé se lówó. Kí a fí mú ya àwòrán bí ojo òla yió tí rí fún ilé-isé fún ìtèsíwájú ilé-isé.

A gbòdó dá èka ètò sílè látirí dájú pé òfín àti ìlànawá bàkàná, èyí tí yíò mú kí isé dí síse fún ìtèsìwájú ilé-isé.

Ó pon dándán pé kía pón omi sílè de òun gbe nítorí àwon ohun tí a kò rò télè tí ò lè yojúlójijì.

Gbogbo ìgbésè kànkan ni kí adarí èka kànkan mo dájúdájú, kí wón bal è se isé won nínú oun tí akosílè fún èka tí won.

Ànfààní wà fún olorí elékajèka láti se àfikún òfin tàbí liana ní èka tire, kí ìlosíwájú lè dé bá èka èyí tí wón ti fi se olórí. Àwon alábójútó wón yìí ní olórí tí wón máa n jábò fún. Nípa bí isé se ún lo àti àwon ìsòro tí wón n kojú ní èka isé tí won; pàtàkì jùlo ní wípé èdùn okàn won tàbí ohun tí wón nílò ní won yíó bèrè lówo alábójútó àgbà.

Nítorínà àwon alábòjútó àgbà gbodò ní ìrírí àti ìmò nípa isé tí wón yàn láayò. Oro ajé ní àdúgbò gbódò je wón lógún, nítorí wípé ólè pa isé won lára.

Gbogbo ìpinu won gbódò jé èyí tí ó jé wípé won yíò mú lò pún ìgbà tí pé. Àwon gba-an ni agbáterù gbogbo ètò ilé-ìsé náà!

Won yíó daa èrò won rò láti ríi dájú pé wón fì dí mulè èyí tí yíó wúlò fún ojó iwájú.

Àwon olórí èká kànkan a máa gbìyànjú pé kí àse láti òdo ògá won di àmúlò. Bí wón bá se ìlànà ti ara won fún ìgbà ni ìwúlò àti ànfààni rè yíò je.


aa - ab - af - ak - als - am - an - ang - ar - arc - as - ast - av - ay - az - ba - bar - bat_smg - bcl - be - be_x_old - bg - bh - bi - bm - bn - bo - bpy - br - bs - bug - bxr - ca - cbk_zam - cdo - ce - ceb - ch - cho - chr - chy - co - cr - crh - cs - csb - cu - cv - cy - da - de - diq - dsb - dv - dz - ee - el - eml - en - eo - es - et - eu - ext - fa - ff - fi - fiu_vro - fj - fo - fr - frp - fur - fy - ga - gan - gd - gl - glk - gn - got - gu - gv - ha - hak - haw - he - hi - hif - ho - hr - hsb - ht - hu - hy - hz - ia - id - ie - ig - ii - ik - ilo - io - is - it - iu - ja - jbo - jv - ka - kaa - kab - kg - ki - kj - kk - kl - km - kn - ko - kr - ks - ksh - ku - kv - kw - ky - la - lad - lb - lbe - lg - li - lij - lmo - ln - lo - lt - lv - map_bms - mdf - mg - mh - mi - mk - ml - mn - mo - mr - mt - mus - my - myv - mzn - na - nah - nap - nds - nds_nl - ne - new - ng - nl - nn - no - nov - nrm - nv - ny - oc - om - or - os - pa - pag - pam - pap - pdc - pi - pih - pl - pms - ps - pt - qu - quality - rm - rmy - rn - ro - roa_rup - roa_tara - ru - rw - sa - sah - sc - scn - sco - sd - se - sg - sh - si - simple - sk - sl - sm - sn - so - sr - srn - ss - st - stq - su - sv - sw - szl - ta - te - tet - tg - th - ti - tk - tl - tlh - tn - to - tpi - tr - ts - tt - tum - tw - ty - udm - ug - uk - ur - uz - ve - vec - vi - vls - vo - wa - war - wo - wuu - xal - xh - yi - yo - za - zea - zh - zh_classical - zh_min_nan - zh_yue - zu -