Karl Marx
Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Adeyemi
Lérè Adéyemí
Tíórì Lítírésò Ní Èdè Yorùbá
Isamulo tiori litireso
Tiori asatako imunisin
Tiori isegbefabo
Sosioloji litireso ti o tele ero Karl Marx
[s'àtúnṣe] Sosiolójì Lítírésò tó tèlé Èrò Karl Marx Ojú-Ìwé 36-39.
Tíórì sosiólójì tó tèlé ìlànà àti èrò Karl Marx kì I se tíórì oni, ó ti pé ti ó tí dáyé. Oludasile tíórì yìí ni Karl Marx. Orúko rè ní àwon abenugan tíórì náà fí n pe ìlànà won. Láti nnkan bí odún 1840 ni Karl Marx fúnra rè ti se èkúnréré àlàyé lórí awujo ati àsà, sùgbón ní nnkan bí Séntúrì ogún ni tíórì náà búréke láwùjo àwon akadá.
[s'àtúnṣe] Tíórì ìsègbèfábo Ojú-Ìwé 40-52.
Tíórì ti a pè ni ìsègbèfábo lédè Yorùbá ni èdè Gèésì pè ni “Feminism”. Láti inú èdè Látìnì ni èdè Gèésì ti ya òrò náà lò èyíni “Femina”- ó túmò sí ohun gbogbo tó je mó abo tàbí àwon obìnrin. Ògíní (1996:11) so pé ònà méjì ni àlàyé lórí tíórì yìí lè pín sí.
[s'àtúnṣe] Tíórì Asàtakò Ìmúnisìn Ojú-Ìwé 53-57.
Tíórì Asàtakò imúnisìn jé tíórì lítírésò àkókó tó kanlè wa fún lámèyító lítírésò àwon orílè èdè tó ti fojú gbooru iná ìjoba amúnisìn télè. Yorùbá bò, won ni, abini tún bini, àbèrè tun bèèrè ni kì í jé ká a pe àbúrò eni lómo eni, gbogbo àwon tíórì lítésò tí a ti tóka sí tàbí se àlàyé rè télè bí ifojuààtò-wò, ìfojú-ìhun-wò títí ó fi de tíórì Makisiisi kò kanlè wà fún lámèyító lítírésò àwon adúláwò tàbí àwon orílè èdè ti kì í se ara Yúróòpù àwon onímò kan wulè n ra tíórì náà bo lítírésò adúláwò lórùn lasan ni.
[s'àtúnṣe] Ìsàmúlò Tíórì lítírésò Mélòó kan Ojú-Ìwé 58-104.
Síse àmúlò tíórì fún lámèyító isé onà alàwòmó lítírésò se pàtakì lóde òní. Lámèyító tí kò bá lo tíórì kan pàtó fún isé rè kò ní ìpìlè tó dúró lé. Irú isé béè kò sí ni wo àjo àwon onímò lámèyító, ko sí ibi ti a kò tí lè lo tíórì fún àlàyé tàbí ìgbélé-wón isé, ewì, eré-oníse tàbí eré-onítàn ìtàn àròso tí o fí kan eré inú fíìmù àgbéléwò tàbí alágbèéká.
[s'àtúnṣe] Tíórì Ìfojú-àsà-ìbílè-wò Ojú-Ìwé 25-26.
Àwon agbáterù tíórì yìí so pé isé tí lítésò máa n se ni láti dáàbò bo àsà àti isese àwùjo kan, nítorí náà ohun tó gbodò je lámèyító lógún ni síse àfihàn irú àwon àsà tó súyo nínú isé onà aláwòmó lítírésò. Ojògbón Wándé Abímbólá so pé:
Therefore, in order to envolve an acceptable format for the appreciation of oral literature, we must blend our knowledge of the most up-to-date tecxxhniques of literary criticism and stylistics with a thorough understanding of Yoruba culture. Without this, any critical work is bound to be sterile.
(Kí a tó lè ri ìlànà lámèyító lítírésò ti yóò jé ìtéwógbà, a niláti jé ki irú ìlànà béè, bí o ti wù ki ó jé ti òde òní tó, ni owó àsà Yorùbá nínú, bí béè kó òfégè lásán ni isé lámèyító béè yóò jé (1982:78)
[s'àtúnṣe] Tíórì Ìfojú-ìtàn-ìgbesi-ayé ònkòwé-wò Ojú-Ìwé 27-28.
Tíórì mìíràn tí ó tún se pàtàkì ni tíórì tí ó n sòrò nípa ìtàn ìgbésí ayé ònkòwé. Ohun tí tíórì yìí so nip é láti se àtúpalè isé onà kan, ó se pàtàkì láti mo irú eni tí ó se náà, ìtàn ìgbésí ayé rè àti àwon nkan mìíràn tó kó ipa pàtàkì kí eni náà tó dáwó lé isé náà àti ohun tí ó mú kí ó gbé isé náà gba ìlànà tí ó gbé e gbà.
[s'àtúnṣe] Tíórì Ìfojú-ìmò-ìbára-eni-gbé-po-wo-lítírésò tàbí sosioloji lítésò Ojú-Ìwé 29-35.
Òrò tí a pè ní Sosiólójì lítírò jé òrò tí onímò èrò ìjìnlè kan ti à n pè ní Taine omo orílè èdè Faranse ro fúnra rè. Onísé lámèyító ni Taine láàárín odún 1828-1893. Ète láti so àgbéyèwò isé onà dàbí ti ìmò sáyénsì ló fa ìsèdá Sosiólójì lítírésò. Ìmò tuntun sì ló jé lágbooloé èkó nípa isé onà.
[s'àtúnṣe] iwe ti a yewo
Lérè Adéyemí (2006) Tíórì Lítírésò Ní Èdè Yorùbá Sgevuituni Shebiotimo Publications, Ijebu-Ode, Nigeria; ISBN: 978-2530-78-6.