Ifọ̀rọ̀wérọ̀
Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́
ÌFÒRÒWÉRÒ
Ìfòròwérò jé òrò láàárín ènìyàn méjì tí ó sí mú ìtumò dání, bóyá nípa kíko sílè tàbí ìtàkuròso. Àtún lè pe ní síse pàsípàrò òrò láàárín ènìyàn méjì tàbí láàárín egbé.
Ìfòròwérò le da lórí eré-oníse díè tí ó mú ìmòràn dání. Láti lé jé kí olùkowé fi èròngbà tàbí àfòjúsùn re hàn. Sùgbón enití ó ní ìfé láti dúró lórí àga ìwásù, àti láti lè gbà àwon ènìyàn ní ìyànjú nípa ohun tí olùkòwé ko láti se alàyé lé lórí.
Ìfòròwérò tún yàn-nà-ná ìwà àwon omo ènìyàn tàbí èrò won tí kò sé fi enu so, nígbàkúgbà, ìwé ìrántí tún se àfihàn ohun tí a ti so síwájú tàbí tí a fi ogbón orí gbé kalè.
Ní ònà mìíràn èwè, ìfòròwérò tún lè wáyé nípa ìwé ìrídìí n kan tí ó ti selè séhìn yìó sí farahàn gégé bí ìfòròwérò. Pèlúpèlú, nípa isé onà opolo, ohun tí á n pè ní ìfòròwérò àwon òjògbón gbe jèwò wón sì ri pé ó jé ti ònà èkó àti Ogbón.
OHUN ÀTIJÓ ÀTI ÌGBÀ YÍÌ
Ní gbà àtijó, a o ri pé ònà tí a fi n gbà bá ara wa sòrò tàbí se ìfòròwérò kò lo danin-danin a lè se ìfòròwérò ní ohun tí a gbó, tí a sé àkosílè rè àti èyí tí à fi ránsé, Èyí kò kú ojú òsùwòn tó ló mú kí àwon òjògbón àti àwon aláwò fúnfun se òpòlopò akitiyan láti je kí ìfòròwérò jé ohun tí yoo rorùn tí yoo sì wúlò púpò nípa bí bá ara wa sòrò ní ònà-konà. Báyìí ni won se sètò ohun èlò ìbánisòrò lóríìsírísi bíi Lítírésò eré àpinlèko, eré oníse, èro ayélujára abbl.
Ní òde òní, a n lo ìfòròwérò nínú jàrá ìkàwé, ní agbègbè wa, ní ilé-isé, àwon tí ó n sojú ìjoba àpapò (federal agencies) àti àwon míràn mú kí ènìyàn pàápàá láàárín àwon ará ìlú kéréje kéréje láti lé jè kí won fòròwérò nípa ìrírí won tàbí èròngbà won lórí ohun tí o bá takókó tábì rújú.
Ó tún jé kí órannilówó láti jé kí á fi òpín sí àwon tí ó bá wà láàárín àwon ènìyàn tàbí agbèègbe wa, láti gbé òye ìjìnlè kalè, mú ìfé dúró láàárín won. ìfòròwérò kíì se fún ìdájó, òduwòn àti síse ìpìninu, sùgbón ó wà fún òye àti èkó kíkó. Ìfòròwéró sí má n lé ìwá àìsòótó jìn-nà; ó sì ma n fi òtító múlè àti láti si ojú ìwòye ènìyàn sí ohun tí ó n lo ní agbègbè won àti àwon ìrírí tí ó jàtò sí ti won.
Lákòótán, ìfòròwérò jé nkan elegé, òpòlopò ìdíwó ni ó rò mo ìfòròwérò bíi kí a soro ìdojú-kojú, òrò àrí-yànjiyàn. Àwon ìdíwó péèpéè bíi: ìbèrù, fífi agbára eni han, àìgbagbó, ìfipámúni abénú, ìdàmú àti òrò tí kó múná dóko, àwon nkan wónyì leè mú kí Ìfòròwérò má le tètè rú jáde