Hinduism
Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Èsìn-ìn Híndu
Hindu ni èsìn ti ó lójó lórí jùlo, tó si lààmi-laaka jùlo nínú gbogbo àwon èsin. Ònà láti se èkúnréré àlàyé ìdàgbàsóké èsìn Hindu ta kókó púpò nítorí pé a kòlè so pàtó eni tó se agbáterù ìdásílè rè sùgbón inú àwon ìse èsìn èyà Aryan ti wón si lo si orílè-èdè India láti ààrin gbùngbùn Asia ló ti sè wá ní bi i i egbèrún odún méta séyìn. Àwon èyà Aryan gbógun ti àwon aráa Arapánì ti wón gbé ni orilè èdè India tòní ni bíi odún 500BC Séyìn. Àsèyín wá, àsèyìn bò, nípa ìfaramolé pèlú ìgbàgbó èsìn keji, àwon èyà méjéèjì se àgbékalè ìlànàn ìgbàgbó èsìn kan ná-àn to dálóríi ìgbàgbò pé èyà Aryan ni ju olórun kan lo àti ìwà ni mímó ìsèso, èyà Hárápáni. Láìpé, àwùjo to kún fún èyà Aryàn se àgbédìde ìlànà ti kò fààyè gba èyà mìíràn wón si se ìpínrò àwùjo won gégé bi isé owóo won se lóóòrìn sí.
Èsin Hindu dá lóri pé èmi ènìyàn àti èmi, eranko to ti kú sí n padà wá sáyé láti máa gbé láimo iye ìgbà àti ni orísiirísii ònàn. Ìgbàgbó pé èmi n lo sókè sódò lónà ta ò le so ni pàtó nipa ìwà èyi tí àwon Hindu yàn je yo nínú àwon àgbékalè isesi won. Ìlànàn ti kò fi àyè gba irúfé èyà miiràn yè, a kò sì gbo rárá pé èya kàn yónú si èyà kejì nítorí pé enikòòkan won ló n du ipò láwùjo ti a gbé bii. A fi elòmíràn si àwùjo tó ga jùlo nítorí pé ó ti hùwà omolúàbí séyìn, ní gbà ti a bi elòmiràn si àwùjo tó tòsi nítorí pé ó ti siwà hù séyìn.
Lónìí, elésin-ín Hindu le gbàgbó pé olórun jù òkan lo, òmíràn lè gbà pé òkan nì, a tún lerí èyi ti ó gbàgbó pé òkan ni olórun àti gbogbo àgba nlá ayé, béè a si tún ri èyi tó gbà pé kò si olorún rárá. Èyi mú ki ó sòro láti jiròrò lórii ìgbàgbó èsìn-in Hindu ni pàtó niwòn ìgbà tó jé wí pé orísiirísii ni òye tó wà nípa èsin Hindu. Nítorí ná-àn à gbodò má ménu ba àwon kókó wònyí.
Pàtàkì, si èsin, Hindu ni ètò ayé àtúnwá, èto èyà ti kò fi àyè gba òmiràn, tó dàpò pèlú ìsèlè tó lààmi laaka, wiwá ìwà omolúàbi àti bibó lówó sikún ayé àtúnwá lálàáfíà.
Lára àwon ònàn èsìn Hindù si igbàlà ni ònàn ìrúbo, mímo àwon ìsèlè tòóótó, ònàn ìfara eni ji, ìfara eni ji fún olórun èyi tó yàn láti tèlé. Bi àwon elésìn yii bá tèlé àwon ààlà àwon ònàn yi, ìgbàlà yóò jé tiwon.