Web Analytics Made Easy - Statcounter

See also ebooksgratis.com: no banners, no cookies, totally FREE.

CLASSICISTRANIERI HOME PAGE - YOUTUBE CHANNEL
Privacy Policy Cookie Policy Terms and Conditions
Health - Wikipedia

Health

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́

ILERA (HEALTH)

Yorùbá bò wón ní ìlera lorò. Ení lówó tí kó ní àlàafíà, onítòhún wá ayé asán nì. Tí a bá ní kí á fi ojú sùnùkùn wo òrò ìlera, tí a sì fé fi ti ènìyàn lásán sòrò lée lórí. A lè so wí pé ìlera jé ètò ìmúláradá, èyí tí ó túmò sí wíwá ní àlàáfíà ènìyàn sùgbón tí a bá ní kí á fi ojú òmòwé tàbí ti olóye wo òrò náà, ó pakaso.

Ìlera jé òrò tí ó fejú láti yàn-nà-ná ni èyí tí ìrònú sì ti wà lóríi rè fún àìmoye odún. Àwon ìlànà à n tèlé méjì kan wà ní àgbékalè fún bí a se le sòrò lé ìlera, ní èyí tíí se “ìlànà ìmò ìsègùn òyìnbó” ati “ìlànà mímó”.

Láti North Amérícà ní ìsègùn òyìnbó, ó jé ìtéwógbà ní ilè North Amérícà ní gbogbo ìgbà. Ní ìbámu pèlú òrò tí a ní láti tún tò tí ó bá dàrú.

Ó fi yé wa wí pé títójú àìsàn àfojúrí kò dára tó fún ìsòro opolo tàbí àwùjo àti kíkàn gbàngbàn nínú titan ìsòro ìlera. Èyí jásí sise àtúpalè ìlera lónà àìtó, bíi àpere: nípàsè àìsàn tàbí iye ènìyàn tí ó kú. Ní ipasè èyí, a lè so pé ìlera túmò sí àìsí àrùn àti kí ara se ojúse tí ó lágbára. Ìgbésè lórí ìdára-eni-lójú; agbára láti jìjàgbara pèlú ìrèwèsì tí ó lè tara ìrònú okàn jáde.

Ní ìlànà pèlú ìlera àwùjo, ìlànà ìsègùn le pe ìlera àwùjo gégé bíi òkan tí ó jé wí pé gbogbo ènìyàn inu rè ní àlàáfíà. Ní ònà mííràn, àtúnse àfiwé le jeyo nínú àwùjo fún ra a rè: àwùjo tí ó ní àlàáfíà jé òkan gbòógì tí gbogbo nnkan bii òrò ajé, òfin, àti béè béè lo kò méhe.

Ní ìbámu pèlú ìlànà mímó; ìlera jeyo láti ara ìtúpalè ìgbìmò káríayé tí n mójú tó ìlera (WHO) tí odún 1947. Ìlànà yìí jé kí èrò àwon onímò ìsègùn gbòòrò sí i, tí ó sì mú èrò ìlera tí ó dántó wá (sùgbón WHO kò lo ìlànà náà). A ka ìtúpalè WHO sí èyí tí ó gbóúnje fégbé. Èyí jeyo Nítorí wí pé kò sí eni tí ó nílò ìwádìí tí ó tako ti àwon onímò ìsègùn. Síso pò mó ènìyàn tí ó wà ní agbègbè ìlànà mímó yóò tún topinpin wíwà dáradára gbogbo ènìyàn ní àpapò.

Ìtúpalè ìlera lè jé gégé bíi ìgbìyànjú oníkálùkù, mòlébí, àkójopò àti àwùjo láti jerí ìsòro-kí-ìsòro tí ó le máa kojúu won. A tún lè so pé ìlera jé “àsìkò tí ènìyàn àti gbogbo nnkan abèmí tí wón jo ní àsepò bá wà títí ayé.

Tí a bá fi ojú sùnùkùn wo àwo ohun tí a ti gbé yèwò nípa ìlera, a ó ri wí pé ìlera se pàtàkì nínú ìgbé ayé gbgbo ènìyàn pátápátá.Bí a se ní ìgbàgbó wí pé tí kò bá sí owó, ènìyàn kàn wá ilé-ayé lásán béè gégé ní ìlera jé eni tí ó bá wá ní ayé tí kò ní àlàáfíà, eni náà ti di òkú.


aa - ab - af - ak - als - am - an - ang - ar - arc - as - ast - av - ay - az - ba - bar - bat_smg - bcl - be - be_x_old - bg - bh - bi - bm - bn - bo - bpy - br - bs - bug - bxr - ca - cbk_zam - cdo - ce - ceb - ch - cho - chr - chy - co - cr - crh - cs - csb - cu - cv - cy - da - de - diq - dsb - dv - dz - ee - el - eml - en - eo - es - et - eu - ext - fa - ff - fi - fiu_vro - fj - fo - fr - frp - fur - fy - ga - gan - gd - gl - glk - gn - got - gu - gv - ha - hak - haw - he - hi - hif - ho - hr - hsb - ht - hu - hy - hz - ia - id - ie - ig - ii - ik - ilo - io - is - it - iu - ja - jbo - jv - ka - kaa - kab - kg - ki - kj - kk - kl - km - kn - ko - kr - ks - ksh - ku - kv - kw - ky - la - lad - lb - lbe - lg - li - lij - lmo - ln - lo - lt - lv - map_bms - mdf - mg - mh - mi - mk - ml - mn - mo - mr - mt - mus - my - myv - mzn - na - nah - nap - nds - nds_nl - ne - new - ng - nl - nn - no - nov - nrm - nv - ny - oc - om - or - os - pa - pag - pam - pap - pdc - pi - pih - pl - pms - ps - pt - qu - quality - rm - rmy - rn - ro - roa_rup - roa_tara - ru - rw - sa - sah - sc - scn - sco - sd - se - sg - sh - si - simple - sk - sl - sm - sn - so - sr - srn - ss - st - stq - su - sv - sw - szl - ta - te - tet - tg - th - ti - tk - tl - tlh - tn - to - tpi - tr - ts - tt - tum - tw - ty - udm - ug - uk - ur - uz - ve - vec - vi - vls - vo - wa - war - wo - wuu - xal - xh - yi - yo - za - zea - zh - zh_classical - zh_min_nan - zh_yue - zu -