Web Analytics Made Easy - Statcounter

See also ebooksgratis.com: no banners, no cookies, totally FREE.

CLASSICISTRANIERI HOME PAGE - YOUTUBE CHANNEL
Privacy Policy Cookie Policy Terms and Conditions
Fotoyiya - Wikipedia

Fotoyiya

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Fótò Yíyà

Fótò yíyà ni ó jè jáde nínú èdè Gíríkì, fótò túnmò sí ìmólè, yíyà túnmò sí yáya nnkan. Ní kíkún, fótò yíyà lápapò túnmò si yíya àwòrán nípa ìmólè.

Fótò yíyà yí kò lè wáyé láìsí àpótí ìyàwòrán tí a fi n ya fótò yí kí ó to wuyì lójú. Àwon onímò ìjìnlè bíi Nicephore Niepce ni odún 1826 ni ó gbá ìmò jo kí àpótí ìyàwòrán yí tó lè wáyé. Sùgbón sáájú àkókò yí ni a ti n rí àwòrán àfowóyà. Èyí mú kí àwon òjògbón bí Ibn al.Haytam (964-1040), Albetus Magnus (1193-1280), Georgea Fabricius (1516-1571), Daniel Barbaro (1560) Wilhalm Homberg se àpèjúwe bí ìmólè se n mú kí àwon kémíkà dá dúdú ní odún 1694 gbìyànjú láti ri wípé won se ero ìgbàlódé tí yóò ma fi àwòràn hàn. Àpapò Àlá àwon òjògbó wònyí bérè síi wa si ìmúse ni odún 1820 tí wón se kéníkà fún Fótò yíyà. Fótò àkókó tí a gbé jáde ni odún 1826 nípa ìrànlówó arákùnrin àrà faransé tí orúko re nje Nicephore Niepce.

Kí tilè ni ìwúlò fótò yíyà ní àwùjo wa lónìí? Fótò yíyà wúlò fún àwon onímò ìjìnlè àti àwon ayàwòrán. Fún àwon ayàwòrán, won máa n lo lati ya nnkan àfojúrí. Ní àwùjo tí a wà yí, olúkúlùkù ènìyàn ni fótò yíyà yí wúlò fún ní ònà kan tàbí ònà mìíràn.

Àwon ológun, olóòpàá àti àwon alàbò n lo Fótò yíyà fún ìsàyèwò àyíká, ìdámò àti fún ìpamó. Fún àwon ènìyàn àwùjo, fótò yíyà se pàtàkì sí won nítorí ó n mú kí wón rántí ipò, àyè àti àkókò tí won fe máa rántí sí ní ìgbésí aye won. Kìí se bé nìkan, ó tún wúlò láti so ìtàn nípa ohun tí ó tí selè sájú àwon ìran mìíràn ti ìtàn náà kò se ojú won. A tún lè lo fótò láti ránsé sí àwon ènìyàn tàbí enìkan tí kò sí ní àrowótó wa. Nípa béè a ó jè kó mò nípa ohun tí ó n selè ní àyíká wa.

A tún lè lo fótò láti se àlejò ní òpò ìgbà, nígbàtí a bá kó fótò fún àlejò láti wò, lópò ìgbà inú irú àlejò béè máa n dùn sí i láti wòó nítorípé gbogbo ènìyàn ni ó fé láti fún ojú lóunje.

Àwon orísi ènìyàn mìíràn máa n lo fótò yíyà fún ara won, ebí won àti àwon òré won. Nígbà tí àwon mìíràn máa n ló lati fi se isé se. Fún àwon ilé-isé, wón máa n lo Fótò yíyà lati fi polówó ojà won tàbí ohun tí wón-n tà. Èyí sì ti mú ìdàgbàsókè bá òpòlópò orò ajé ilé isé ní àgbáyé.

A ní orísi fótò méjì: Fótò oní dúdú àti funfun a si tún ni fótò aláwò. Fótò oní dúdú àti fuinfun ni o kókó wáyé nígbàná-án lóhùn-ún. Sùgbón nígbàtí ìmò-ìjìnlè tè síwájú, ni a se àgbékalè fótò aláwò ti o gbalégboko lónìí yìí.

Bàwo ni a se n ya Fótò? Fótò yíyà kìí se láti sáná mo ènìyàn lójú, sùgbón ó ní mímòóyà. Kí a tó lè ya fótò, a gbódò ti ri wípé enití tí a fé yà ti dúró dáradára ki a to ya irú eni béè. Ònà miràn ti a gbódò mò nígbàtí a bá fé ya fótò nipé: se fótò aláàbò ni tàbí aláworán tí ó délè.

Fótò yíyà ni àwùjo wa lónìí ti wá da ìlúmòóká tí tàgbà tomodé ti wá mo ìwúlò rè. Sùgbón kìí se isé tí a lé ku gbùù se lai mo ìgbésè tí a nílò láti tò. Nítorínáà, ó se pàtàkì fún eni tí ó bá fé fi fótò yíyà se isé òòjó rè mo àpadépayo isé náà tí ó bá fé se àseyorí nínú rè.


aa - ab - af - ak - als - am - an - ang - ar - arc - as - ast - av - ay - az - ba - bar - bat_smg - bcl - be - be_x_old - bg - bh - bi - bm - bn - bo - bpy - br - bs - bug - bxr - ca - cbk_zam - cdo - ce - ceb - ch - cho - chr - chy - co - cr - crh - cs - csb - cu - cv - cy - da - de - diq - dsb - dv - dz - ee - el - eml - en - eo - es - et - eu - ext - fa - ff - fi - fiu_vro - fj - fo - fr - frp - fur - fy - ga - gan - gd - gl - glk - gn - got - gu - gv - ha - hak - haw - he - hi - hif - ho - hr - hsb - ht - hu - hy - hz - ia - id - ie - ig - ii - ik - ilo - io - is - it - iu - ja - jbo - jv - ka - kaa - kab - kg - ki - kj - kk - kl - km - kn - ko - kr - ks - ksh - ku - kv - kw - ky - la - lad - lb - lbe - lg - li - lij - lmo - ln - lo - lt - lv - map_bms - mdf - mg - mh - mi - mk - ml - mn - mo - mr - mt - mus - my - myv - mzn - na - nah - nap - nds - nds_nl - ne - new - ng - nl - nn - no - nov - nrm - nv - ny - oc - om - or - os - pa - pag - pam - pap - pdc - pi - pih - pl - pms - ps - pt - qu - quality - rm - rmy - rn - ro - roa_rup - roa_tara - ru - rw - sa - sah - sc - scn - sco - sd - se - sg - sh - si - simple - sk - sl - sm - sn - so - sr - srn - ss - st - stq - su - sv - sw - szl - ta - te - tet - tg - th - ti - tk - tl - tlh - tn - to - tpi - tr - ts - tt - tum - tw - ty - udm - ug - uk - ur - uz - ve - vec - vi - vls - vo - wa - war - wo - wuu - xal - xh - yi - yo - za - zea - zh - zh_classical - zh_min_nan - zh_yue - zu -