Web Analytics Made Easy - Statcounter

See also ebooksgratis.com: no banners, no cookies, totally FREE.

CLASSICISTRANIERI HOME PAGE - YOUTUBE CHANNEL
Privacy Policy Cookie Policy Terms and Conditions
Culture - Wikipedia

Culture

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́

ÀSÀ YORÙBÁ

Àsà ni ohun gbobgo tó je mó ìgbé ayé àwon asùwàdà ènìyàn kan ni àdúgbò kan, bèrè lórí èrò, èdè, èsìn, ètò ìsèlú, ètò orò ajé, ìsèdá ohun èlò, ìtàn, òfin, ìse, ìrísí, ìhùwàsí, onà, oúnje, ònà ìse nnkan, yíyí àyíká tàbí àdúgbò kòòkan padà. Pàtàkì jùlo èsìn ìbílè, eré ìbílè àti isé ìbílè ni a lè pè ní àsà. Ohun ti o je orírun àsà ni ‘àrà’, ó lè dára tàbí kí ó burú. Ìpolówó Èkìtì – iyan rere, obe rere; Ipolowo Ondó Ègin – (dípò Iyán) èbà gbon fee. Àsà Ondó ni kí wón máa pe iyán ni èbà nítorí pé èèwò won ni, won kò gbódò polówó iyán ni àárín ìlú. 

Àsà je mó ìgbàgbó àpeere; àbíkú, àkúdàáyá. Àsà je mó isé onà ti a lè fojú rí tàbí aláfenuso. A lè pín àsà sí ìsòrí méta èyí tí ó je mó:

(a) Ogbón ìmò, ète tàbí ètò tí a ń gbà se nnken, àpeere ilà kíko, irun dídì abbl.

(b) Isé onà bíi igi gbígbé

(d) Bí a se ń darí ìhùwàsí àwon egbé/èyà kan Ara àbùdá àsà ni pé: Kò lè súyo láìsí ènìyàn; èmí rè gùn ju ti ènìyàn lo; Ó je mó ohun tí a fojúrí; Àsà kòòkan ló ní ìdí kan pàtó; Àlàyé wà nípa àsà. Àsà lè jeyo nínú oúnje: Òkèlè wó pò nínú oúnje wa. Àkókó kúndùn èbà, Ìlàje-pupuru, Igbó orà-láfún. Àsà lè jeyo nínú ìtójú oyún/aláìsàn/òkú; ètò ebí/àjosepò; ètò ìsàkóso àdúgbò, abúlé tàbí lara dídá nípa isé onà. Bí ó tilè jé pé àsà máa ń yí padà nípa aso wíwò, ìgbeyàwó abbl lóde òní ètò èkó àti ìwà òlàjú tó gbòde kan ti se àkóbá fún àsà ní ònà yìí:

(a) Ìwoso wa kò bójú mu mó

(b) Àsà ìkíni wa kò ní òwò nínú mó

(d) Kí’yàwò ilé má mo oúnje ìbílè sè mó

(e) A kò mo ìtumò àrokò tí a ń kó àwon omo wa mó.

Àwon ònà tí àsà máa ń gbà yí padà nì wònyí:

(a) Bí àsà tó wà nílè bá lágbára ju èyí tó jé tuntun lo, èyí tó wà télè yóò borí tuntun, àpeere aso wíwò.

(b) Àyípadà lè wáyé bí àsà tó wà nílè télè bá jé dógbandógba pèlú àsà tuntun, wón lè jo rìn papò, bí àpeere àsà ìgbéyàwó.

(d) Bí àsà tuntun bá lágbára ju èyí tó wà nílè télè, yóò so àsà ti àtèhìnwódi ohun ìgbàgbé, àpeere bí a se ń kólé.

Tí a bá wá wò ó fínnífínní, a ri wí pé àsà lópòlopò ìtbà máa ń dá lé:

(a) Ìmò isé sáyénsì

(b) Ìse jeun wa

(d) Ìsowó kólé

(e) Isé owó ní síse

ÀKÍYÈSI:-

Èdè àwon ènìyàn jé kókó kan pàtàkì nínú àsà won. Kò sí ègbón tàbí àbúrò nínú àsà àti èdè. Ìbejì ni wón. Ojó kan náà ni wón délé ayé nítorí pé kò sí ohun tí a fé so nípa àsà tí kì í se pé èdè ni a ó fi gbé e kalè. Láti ara èdè pàápàá ni a ti lè fa àsà yo. A lè fi èdè Yorùbá so ohun tó wà lókàn eni, a lè fi korin, a lè fi kéwì, a lè fi jósìn àti béè béè lo. Láti ara àwon nnkan tí a ń so jáde lénu wònyí ni àsà wa ti ń jeyo. Ara èdè Yorùbá náà ni òwe àti àwon àkànlò-èdè gbogbo. A lè fa púpò nínú àwon àsà wa yo láti ara òw àti àkànlò èdè. Nítorí náà, èdè ni ó jé òpómúléró fún àsà Yorùbá àti wí pé òun ni ó fà á tí ó fi jé wí pé bí àwon omo Odùduwà se tàn kálè, orílè-èdè kan ni wón, èdè kan náà ni wón ń so níbikíbi tí wón lè wà. Ìsesí, ìhùwàsí, àsà àti èsìn won kò yàtò. Fún ìdí èyí, láísí ènìyàn kò lè sí àsà rárá.

REFERENCE TEXTBOOKS:

1. Adeoye C.L. (1979) Àsà àti ise Yorùbá Oxford University Press Limited

2. J.A. Atanda (1980) An introduction to Yoruba History Ibadan University Press Limited

3. Adeomola Fasiku (1995) Igbajo and its People Printed by Writers

                               Press Limited 

4. G.O. Olusanya (1983) Studies in Yorùbá History and Culture Ibadan University Press Limited.

5. Rev. Samuel Johnson (1921) The History of the Yorubas A divisional of CSS Limited.


aa - ab - af - ak - als - am - an - ang - ar - arc - as - ast - av - ay - az - ba - bar - bat_smg - bcl - be - be_x_old - bg - bh - bi - bm - bn - bo - bpy - br - bs - bug - bxr - ca - cbk_zam - cdo - ce - ceb - ch - cho - chr - chy - co - cr - crh - cs - csb - cu - cv - cy - da - de - diq - dsb - dv - dz - ee - el - eml - en - eo - es - et - eu - ext - fa - ff - fi - fiu_vro - fj - fo - fr - frp - fur - fy - ga - gan - gd - gl - glk - gn - got - gu - gv - ha - hak - haw - he - hi - hif - ho - hr - hsb - ht - hu - hy - hz - ia - id - ie - ig - ii - ik - ilo - io - is - it - iu - ja - jbo - jv - ka - kaa - kab - kg - ki - kj - kk - kl - km - kn - ko - kr - ks - ksh - ku - kv - kw - ky - la - lad - lb - lbe - lg - li - lij - lmo - ln - lo - lt - lv - map_bms - mdf - mg - mh - mi - mk - ml - mn - mo - mr - mt - mus - my - myv - mzn - na - nah - nap - nds - nds_nl - ne - new - ng - nl - nn - no - nov - nrm - nv - ny - oc - om - or - os - pa - pag - pam - pap - pdc - pi - pih - pl - pms - ps - pt - qu - quality - rm - rmy - rn - ro - roa_rup - roa_tara - ru - rw - sa - sah - sc - scn - sco - sd - se - sg - sh - si - simple - sk - sl - sm - sn - so - sr - srn - ss - st - stq - su - sv - sw - szl - ta - te - tet - tg - th - ti - tk - tl - tlh - tn - to - tpi - tr - ts - tt - tum - tw - ty - udm - ug - uk - ur - uz - ve - vec - vi - vls - vo - wa - war - wo - wuu - xal - xh - yi - yo - za - zea - zh - zh_classical - zh_min_nan - zh_yue - zu -