Web Analytics Made Easy - Statcounter

See also ebooksgratis.com: no banners, no cookies, totally FREE.

CLASSICISTRANIERI HOME PAGE - YOUTUBE CHANNEL
Privacy Policy Cookie Policy Terms and Conditions
Ẹ̀kọ́ nípa eré-orin - Wikipedia

Ẹ̀kọ́ nípa eré-orin

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Orin

Oladejo Kafaya


` OLADEJO KAFAYA

OHUN TÍ ORIN JE

Ní pàtàkì okan nínú àwon èyà, ewì ní orin jé. Ònà kan ò wojá orísìírísìí ní oríkì tí àwon ènìyàn tí ó jé onímò tí fún orin.

C.M. Bowa so wí pé:-

Songs one purposeful atlempts to put

Into coherent words, thoughts

And feelings which may in their

State be fair from coherent

“Ohun tí a lè pè ní orin ní nnkan

tí a rò lókàn tí a sì ko jáde

nígbà tí o dàbí eni pé a rí àwon

nnkan lo sàjòjì tàbí ju agbára

wa lo; nígbà tí a rò pé òrò enu

lásán kò ní í le sàlàyé bí ohun

yìí se ká wa lára tó.”

ÈKÓ NÍPA ORIN

Orin jé òkan lára lítírésò alòhun Yorùbá sùgbón ní òde-òní òpòlopò àwon lítírésò alohùn Yorùbá ni ó wà ní kíkosílè. A gbà pé lítírésò alòhun ní orin sùgbón kí ní lítírésò? Lítírésò tí ó wà ní opolo àwon bàbá wa lítírésò tía sòrò nípa rè le jé òrò geere, ewì? Eré oníse tàbí onítàn, Àwon oní gèésì kò gbà pé Yorùbá ní lítírésò nítorí ohùn ní àwon Yorùbá fín gbé lítirésò won jáde sùgbón àwon onímò tí o ti fun lítírésò ní oriki, sùgbón oríkì òjògbón Adébójè Babalolá (1967:7):- káàkan àgbáyé ó hàn gbangba pé ohnu tí ń jé lítírésò ní àkójopò òrò ní èdè kan tàbí ìjìnlè òrò tí ó já sí àrofò ìtàn, ewì, àló, ìròyìn tàbí eré onítan, ere akónilógbón sùgbón ORIN ní mo fè woo gégé bí àpeere lítírésò Yorùbá. Orin jé ìkan tí o wópò láàárin àwon Yorùbá nítorí orin jé ìkan tàbí ohun ìdárayá, ere láàrín omodé, a fí orin bá ènìyàn tàbí àwùjo sòrò. Orísìírìsii orin sí lo wa ńilè Yorùbá àpeere orin tí mo fé yèwò ní ORIN ÌGBÉYÀWÓ tí a si mò sí EKÚN ÌYÀWÓ àti ORIN OMODE

ORIN ÌGBÉYÀWÓ

Orin Ìgbáyàwó wópò láàrín àwon Yorùbá nítorí ìgbéyàwó jé ìkan ìdùnú láàárin àwon Yorùbá, ohun èdùn gidi ní ó jé pé púpò nínú gbògbò àti ìdí igi àsà Yorùbá tí a ba wo-wá-wèhìn nípa àsà àti èsìn abínibí àti àdá yébá Yorùbá kòòkan, a o ri i pe àmúlùmálà tí fere gba Yorùbá lowo wa pin, òpòlopò ènìyàn ní o ge ìyàwó tí won tí gbe nípa ekún ìyàwó sùgbón ní ayé àtijó o je ìkan o- kunkudii fún omo tí o losí ilé-oko láti sun-u. ojó ìbànújé papò mo ayò ni, sùgbón lójó yìí ìbànújé a teri ayò ba. ìbànújé yóó te’rí ayò ba nítorí pé odo iya ati bàbá ní omobinrin yìí tí n gbe láti ojó tí a tí bí i, ó mo níní-t’àní àwon òbi re, ó mo àsírí obi re awon obi re mo tire náà. omobìnrin náà ní àyè nílé bàbá re, ki a wa wo sunsun ki a so pe a yo omo náà kúrò bàbá re bí eni yo jiga. Aimo ohun tí omobinrin yóó ba nílé oko, àimò ìwà tí àwon ènìyàn tí o n lo ba níbe yóò máa si i orisiirisii nnkan ni o ma farahan nígba tí omobirin bá sunkún. àpeere méta

(i) lelele ní omobrin yoo maa ké wupe ki àwon obi àti agbaagba o súre fún òun

(ii) pèlu, ekun lójú ní omobinrin yóó maa fí opé àti imoore re han si awon obi re

(iii) pèlú èkun lójú ni omobinrin yoo fi ma se ìdárò ìpínyà oun àti àwon òré rè. láàárò ìyàwó yóò ti bó sóde léyun tí àwon òbí rè bá ti júwe ibi gbogbo tí yóò dé fún un tán àwon egbé rè, omoge tí kò ì woléko yóò tèle léyìn.

Ìyá mí ní d’ódò èyin

Nó gbá ìre tèmi kí n tóó máa lo

Ire owó, ire omo

Ire, kí má fí àbíkú sewó

Ire kí n má rìn rìn se àgbà

Mo bí, mo bí n t’omo kóóko

Mo pò mo pò n’t’ omo mèrùwá

Àbí-jà-gì-lá’jà n’ t’èkútée lé

Ire, àbíkú l’elédèé bí, elégbé mo ní o

Orí ó níí fún mi l’àbì gbìn omo.

Èmí ní ng ó ma máa lo nùun

Èmi àkóbí onídùndún mo olórí osó

N ó máa lo nù-un

N ò nì í lò ìlo eja, t’ ó lo

Tí ò dé’ núu ‘ bú

N ò níí loìlo akàn.

Àní tó lo tí ò d’ odo.


ORIN OMODÉ

Orin omodé náà pò ní orísìírìsi ònà nítorí òrin ní a tí dárayá láàrín àwon. Àwon omodé náà fí orin náà kó ara won lékòó tàbí kí won fí bá ara wón wí lórí ìwà ìbàjé tí wón. Àpeere orin omodé ní :- (i) Búúrù o

(ii) Eni bi eni


(iii) Bóóbo

(iv) Worú Búúrú o, bààrà o,

T’òtún yo, t’o si yo

E p’ara mó o,

T’ agbedeméjì yo fó fó!

Olórò bo o!

T’ohún yo, tòsì yo.

Sé kí n si i?

T’agbedemeji yo fó fó! si í!

WÒRÚ

Wòrú, o, wòrú, oko

Wòrú, ó, wòrú odò

Wòrú pa, ‘ka f’eiye je

Mo dé ilé mo rò fún baba

Baba na wòrú jojo,

Wòrú dà? Eye ti gbé e lo

Lábé ògèdè lábe òrombó

O ti se d’ abe ata

Ide wéwé nit í orisà

Sekesete ni ti ògún

E ba mi kìlò fún bálè

Kí o fún mi lododo pakájà

Gbogbo wa lo’ògún job í o,

ORIN ÌDÁRAYÁ NÍ ILÉ-ÌWÉ ALÁKÒÓBÈRÈ

Nínú àwàdà náà ní a tí ń mo òótó. Ó se pàtàkì láti kókó tóka sí i wí pé àwon àgbà ní ó sèdá àwon orin yìí fún àwon omode tí wón jé omo-ilé ìwé alákòóbèrè. Ète ní won pa láti ko àwon omo ile-ìwé ní èkó ní ònà tí o lè rorùn fún won ju láti máa rántí. Lóòtó ní àwon orin yìí wa fún ìdárayá súgbón síbè, orín yìí nnkan ní wón dá dé lórí ní pàtó, tí wón jé kókó inú àwon omo yìí. 

Àwon kókó inú àwon orin ìdárayá yìí je móàwon àsà àti ìgbàgbó àwon àwon Yorùbá lórísìírísìí, èkó ìwà tí o dára ní àwùjo àtí gbígba omodé ní ìmòràn, àsà ìsèlú, isé òòjó, eré òsùpá {fún ìdárayá} ìmótótó àti ìnáání ohun tí ń se teni. Ohun mìíràn ní ìlànà èkó-ìwé kíkà bí i ìsirà. Ìgbàgbó èsìn òkèère àti ìtáákà èdè. A lè pín àwon kókó yìí sí abé ìsòrí méta

(i) Àsà àti Ìgbàgbó àwon Yorùbá

(ii) Ìlànà èkó ìwé kíkà

(iii) Ìdárayá.

ÀSÀ ÀTI ÌGBÀGBÓ ÀWON YORÙBÁ

Ìgbàgbó Yorùbá á lórí ìbà jújú kì í se kékeré rárá nítorí ÌBÀ jé nkan lára àsà àti ìgbàgbó Yorùbá. Yorùbá gbàgbó nínú ajunilo, nítorí náà ó se pàtàkì láti kó omodé nípa ìbà jújú láti fi pon ènìyàn lé. Tí omodé ba seré, tí àwon àgbà be ń ní ìkàlè, omodé gbódò júbà. Àpeere ìbà jújú ní ilé-ìwé alákòóbèrè:-

Í ba, Í ba, Í ba ba

Ìbà

Ì ba, Ì ba, Ì ba ba

Ìbà

Ìbà fún àwon tó o layé o

Ìbà fún àwon tó nilè o

eni bá jì nínú igbó

a júbà fún eni tó nigbó

Ìbà Ìbà Ìbà Ìbà

Ìbà fún omodé to bá seré

Tí omodé ba júbà àgbà

Ó dájú kò ní í sìse

Eti, Eh, Eh, Eh,.

ÌLÀNÀ ÈKÓ KÍKÀ

Àwon olùkó máa ń lo ìlànà orin láti ko àwon omo-ilé ìwé nì n nkan tí o máa sí won ní opolo. Nkan tí ó mú àwon ohun yìí wa yè ní àsà mò-ón-ko, mò-ónkà

Ìwé kíkó

Láìsí oko àti àdá

Kò ì pé o, kò ì pé ò

Ise àgbè ní isé ilèè wa

eni kò sisé, a màa jalè.

ÌDÁRAYÁ”-

Àwon omo-ilé-ìwe máa ń fí àwon orin dá ara won lára yá. Wón lára le ko irú orin béè láti se èfe tàbí fi se èébú. Àpeere orin ìdárayé láàrín àwon omo ilé-ìwá:-

Kí lagba fún won?

Bóòlù

Kí la lò fún won?

System

Èló la fún won?

4 – 0

(2) Ebí ń pa tísà

Ó yígbó èynìn lo

Tákútè mu lésèè

Ó rugi àkóba

(3) Kin mo fe fí olè se

láyé tí mo wá?

kí mo fé fi olè se

láyé tí mo wá

laiye fí mo wa

kàkà ki jalè

ma kúkú se erú

kí mo fe fí olè se

láyé tí mo wá.

Ení bá jalè a délé ejó

Eni ba jalè a dele ejó

A délé ejó

Adájó a wa fi èwòn tí lesè.


aa - ab - af - ak - als - am - an - ang - ar - arc - as - ast - av - ay - az - ba - bar - bat_smg - bcl - be - be_x_old - bg - bh - bi - bm - bn - bo - bpy - br - bs - bug - bxr - ca - cbk_zam - cdo - ce - ceb - ch - cho - chr - chy - co - cr - crh - cs - csb - cu - cv - cy - da - de - diq - dsb - dv - dz - ee - el - eml - en - eo - es - et - eu - ext - fa - ff - fi - fiu_vro - fj - fo - fr - frp - fur - fy - ga - gan - gd - gl - glk - gn - got - gu - gv - ha - hak - haw - he - hi - hif - ho - hr - hsb - ht - hu - hy - hz - ia - id - ie - ig - ii - ik - ilo - io - is - it - iu - ja - jbo - jv - ka - kaa - kab - kg - ki - kj - kk - kl - km - kn - ko - kr - ks - ksh - ku - kv - kw - ky - la - lad - lb - lbe - lg - li - lij - lmo - ln - lo - lt - lv - map_bms - mdf - mg - mh - mi - mk - ml - mn - mo - mr - mt - mus - my - myv - mzn - na - nah - nap - nds - nds_nl - ne - new - ng - nl - nn - no - nov - nrm - nv - ny - oc - om - or - os - pa - pag - pam - pap - pdc - pi - pih - pl - pms - ps - pt - qu - quality - rm - rmy - rn - ro - roa_rup - roa_tara - ru - rw - sa - sah - sc - scn - sco - sd - se - sg - sh - si - simple - sk - sl - sm - sn - so - sr - srn - ss - st - stq - su - sv - sw - szl - ta - te - tet - tg - th - ti - tk - tl - tlh - tn - to - tpi - tr - ts - tt - tum - tw - ty - udm - ug - uk - ur - uz - ve - vec - vi - vls - vo - wa - war - wo - wuu - xal - xh - yi - yo - za - zea - zh - zh_classical - zh_min_nan - zh_yue - zu -