Web Analytics Made Easy - Statcounter

See also ebooksgratis.com: no banners, no cookies, totally FREE.

CLASSICISTRANIERI HOME PAGE - YOUTUBE CHANNEL
Privacy Policy Cookie Policy Terms and Conditions
Ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá - Wikipedia

Ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Awujo

Soyemi, Oluyinka Benjamin

SOYEMI OLUYINKA BENJAMIN

ÈKÓ NÍPA ÀWÙJO-ÈDÁ

Èkó nípa àwùjo-èdá jé èkó kan pàtàkì tí kò se é fowó ró séyìn. Kò sí èdá alààyè tó dá wà láì ní Olùbátan tàbí alájogbé. Orísirísi ènìyàn ló parapò di àwùjo-bàbá, ìyá, ará, òré, olùbátan ati béè béè lo. Bí ìyá se ń bí omo, tí bàbá ń wo omo àti bí òré àti ojúlùmò se ń báni gbé, béè ni ìbá gbépò èdá n gbòòrò si. Gbogbo àwon wònyí náà ló parapò di àwùjo-èdá. Àti èni tí a bá tan, àti eni tí a kò tan mó, gbogbo wa náà la parapò di àwùjo-èdá. Ní ilè Yorùbá ati níbi gbogbo ti èdá ènìyàn ń gbé, ìbágbépò èdá se pàtàkì púpò. Bí enìkan bá ní òun ò bá enikéni gbé, tí kò bá gbé nígbó, yóó wábi gbàlo. Sùgbón, àwa ènìyàn lápapò mo ìwúlò ìbágbépò. Orísirísi ànfàní ni ó wà nínú ìbágbépò èdá. Bí òpò ènìyàn bá n gbé papò, ó rorùn lati jo parapò dojú ko ogun tàbí òté tí ó bá fé wá láti ibikíbi. Yorùbá bò wón ní àjòjì owó kan ò gbérù dórí. Béè gégé ló se rí fún àwùjo-èdá. Gbígbé papò yìí máa ń mú ìdádúró láì sí ìbèrù dání nítorí bí òsùsù owò se le láti sé, béè ni àwùjo tó fohùn sòkan. Èyí jé oun pàtàkì lára ànfàní tó wa nínú ìsòkan nínú àwùjo-èdá. Nídà kejì, bí òrò àwùjo-èdá ba jé kónkó-jabele, èté àti wàhálà ni ojú omo ènìyàn yóó máa rí. Nítorí náà, ó dára kí ìsòkan joba ni àwujo-èdá. Ìdàgbàsókè tí ó máa ń wà nínú àwùjo kò sèyìn ìfowósowópò bí àti ránmú un gángan ò ti sèyìn èékánná. Ó ye kí á mò pé nítorí ìdàgbàsókè ni èdá fi ń gbé papò. Bí igi kan ò se lè dágbó se, béè náà ni enìkan ò lè dálùúgbé. Òpòlopò ènìyàn ló máa ń dá Ogbón jo fún ìdàgbàsókè ìlú. Bí Ogbón kan kò bá parí isé, Ogbón mìíràn yóó gbè é léyìn. Níbi tí orísirísi ogbón bá ti parapò, ìlosíwájú kò ní jìnnà si irú agbègbè béè. Gbogbo àwon nnkan wònyí jé ànfàní tó wà ní àwùjo-èdá tí kò sì se é fi sílè láì ménu bà. Nínú èkó nípa àwùjo-èdá, a tún máa ń sòrò nípa ìsòro tó ń kojú ìbágbépò èdá. Kò se é se kó máa sì wàhálà láwùjo ènìyàn. A kò lè ronú lónà kan soso, nítorí náà, ìjà àti asò máa ń jé àwon nnkan tí a kò lè sàì má rì í níbi ti àwon ènìyàn bá ń gbé. Wàhálà máa ń fa òtè, òtè ń di ogun, ogun sì ń fa ikú àti fífi dúkàá sòfò. Àwon nnkan wònyí jé ara àwon ìsòro tó n kojú àwùjo-èdá. Kò sí bí ìlú tàbí orílè-èdè kan kò se ní ní òkan nínú àwon àwon ìsòro wònyí. Sùgbón, a gbódò mò wí pé awon ànfàní àti awon ìsòro wònyí ti wà láti ìgbà pípé wá. Tí a bá wo àwon ìtàn àtijo gbogbo, a ó ri pé gbogbo àwon nnkan wònyí kò jé tuntun. Ogbón omo ènìyàn ni ó fi se okò orí-ìle, ti orí-omi àti ti òfúrifú fún ìrìnkèrindò tí ó rorùn. Àwùjo-èdá ti se àwon nnkan dáradára báyìí náà ni wón ń se àwon ohun tí ó lè pa ènìyàn lára. Fún àpeere, ìbon àti àdó-olóró. Àwon ohun ìjà wònyí ni wón lò ní ogun àgbájé kìnní tí o wáyé ní Odun 1914 sí 1918 àti ti èkej


aa - ab - af - ak - als - am - an - ang - ar - arc - as - ast - av - ay - az - ba - bar - bat_smg - bcl - be - be_x_old - bg - bh - bi - bm - bn - bo - bpy - br - bs - bug - bxr - ca - cbk_zam - cdo - ce - ceb - ch - cho - chr - chy - co - cr - crh - cs - csb - cu - cv - cy - da - de - diq - dsb - dv - dz - ee - el - eml - en - eo - es - et - eu - ext - fa - ff - fi - fiu_vro - fj - fo - fr - frp - fur - fy - ga - gan - gd - gl - glk - gn - got - gu - gv - ha - hak - haw - he - hi - hif - ho - hr - hsb - ht - hu - hy - hz - ia - id - ie - ig - ii - ik - ilo - io - is - it - iu - ja - jbo - jv - ka - kaa - kab - kg - ki - kj - kk - kl - km - kn - ko - kr - ks - ksh - ku - kv - kw - ky - la - lad - lb - lbe - lg - li - lij - lmo - ln - lo - lt - lv - map_bms - mdf - mg - mh - mi - mk - ml - mn - mo - mr - mt - mus - my - myv - mzn - na - nah - nap - nds - nds_nl - ne - new - ng - nl - nn - no - nov - nrm - nv - ny - oc - om - or - os - pa - pag - pam - pap - pdc - pi - pih - pl - pms - ps - pt - qu - quality - rm - rmy - rn - ro - roa_rup - roa_tara - ru - rw - sa - sah - sc - scn - sco - sd - se - sg - sh - si - simple - sk - sl - sm - sn - so - sr - srn - ss - st - stq - su - sv - sw - szl - ta - te - tet - tg - th - ti - tk - tl - tlh - tn - to - tpi - tr - ts - tt - tum - tw - ty - udm - ug - uk - ur - uz - ve - vec - vi - vls - vo - wa - war - wo - wuu - xal - xh - yi - yo - za - zea - zh - zh_classical - zh_min_nan - zh_yue - zu -