Ẹ̀kọ́ imọ̀-èdè
Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́
ÈKÓ ÌMÒ ÈDÁ ÈDÈ
Kíni èkó ìmò èdá èdè?
Èkó Ìmò èdá èdè jé ìmò ìjìnlè ìwádìí tàbí kíkó nípa èdè. Ó fún wa ní ìsapá tàbí ìyànjú láti lè dáhùn ìbérè bíi kí ni èdè tàbí láti lè se ìwáàdí ìtumò èdè, àti bí o se rí ní okàn. Àwon onímò èdá èdè ní àfojú sùn lóri sise àlàyé èdè láì wo ìlànà àwon òfin tí ó de èdè. (àílòpin ìlà sí wéwé).
Èkó ìmò èdá èdè, kó fi dandan mú ni kí á mo gbogbo èdè àtipé àwon onímò èdá èdè kíì se ògbufò. Èròngbà àwon onímò èdá èdè ni láti gbìyànjú nípa ìmò àwon ènìyàn, èdè àti àwon àbùdá gbogbo èdè. Àwon onímò ìjìnlè èdè tún gbìyànjú láti mú kí gbogbo ohun àmúye fún èdè wà ní ipò tí ó dára tàbí yanrantí fún lílò èdè gbogbo, àti láti wo àwon ohun tí kò lè séese tàbí wonú èdè.
Èkó ìmò èdá èdè jé ìbákégbépò ìmò pèlú àwon ìmò sááyènsì bíi: Èkó ìmò èrò okàn ènìyàn, Ìmò àwùjo àdáyébá àti ìmò ènìyàn àti agbègberè. O lè mú kí àwon èka míiràn bí èdè gèésì, kíkó èkó ìbánisòrò, èkó nípa ìmò èro ayélujára, èkó ìmò èdá èdè ní ònà míràn a fún le sò pé ó bá èyà sááyènsì mu pèlú ìmò èrò okàn ènìyàn. Ìmò èdá èdè, láì fa òrò gùn ní se pèlú bí opolo ènìyàn ti n sisé.
Ní ìsàlè ni a rí orísiirísi èka ìmò èdá èdè àwon ìlànà fonólójì, fònétíìkì, Mofólójì, síntáàsì, semántíìkì àti àkóónú èdè ni a o gbé yèwò làti mò bí ìmò se se pàtakì tó àti láti moo ìjìnlè èkó yìí.
FÒNÉTÍÍKÌ: Èyí jé èkó nípa ìró èdè, èkó nípa bí a se n pe ìró inú èdè kan nínú fònétííkì ni a ti n kó nípa àwon èyà ara tí a n lò fún ìró èdè pípè àti àmúlò won bóyá nípa gbígbó, pípè, dídún àti èrò ìgbàlódé lílò.
FONÓLOJÌ: Èyí ni mí mo ìwòse àwon èdè ó tún jé ètò àmúlò ìró èdè kòòkan, ìmò nípa ònà ti a n gbà lo ìró èdè. Fonólójì ni ònà ti a n gbá sín àwon ìró pò ní ònà tí ó jé pé yóò fi fún wa ní ìtumò tí ó kúnà.
MOFÓLÓJI: Èyí ni èkó nípa bí a se lè se èdá òrò àti bí a se kó òrò pò làti ibi èyà kékeré àti àwon òfin tí ó de gbogbo ìlànà yíì. Gbogbo ohun tí a kó pò tí ó wá di odidi òrò ni a n pè ní Mofólójì.
SÍNTÁÀSÌ: Ó jé ònà láti se àgbékalè gbólóhùn, ó tún jé ètò láti mo bi a ti se n lo gírámà Yorùbá nínú gbólóhùn pèlú ìlànà òfin bí a se lèe lo òrò ise pèlú òrò orúko, kí ni ìró kónsónátì àti ìró fáwéélì àti bí a ti se le lò won nínú èdè èyí ni a n pè ní síntáàsì.
SEMÁNTÍÌKÌ: Èkó nípa ìtumò ni èyí, bí a se lè gbé ìtumò òrò kalè nínú òkàn wa àti bí a se lè lóó láti ko gbólóhùn èdè Yorùbá jáde tí yóò mú itumò tí ó múnádóko dání. BÍ A SE N NÍ ÌMÒ ÈDÈ: Èyí fihàn wá bí ènìyàn ti le mo èdè kan tàbí òmíràn ó tún lè se ètò bí àwon omodé se n kó láti so èdè àti bí àgbà se n kó èdè míràn. Nínú ìmò èdá èdè se pàtàkì púpò nítorí tí ó fún wa ní a àfojú sùn nínú èkó ìmò èdá èdè, ònà méjì pàtàkì ni a fi lè mo àbùdá èdè òna kíní ni ònà abínibí wa, ònà kejì ni èdè àdúgbò wa tabi àyìíká wa.
ÀWON ÈKA MÍRÀN LÁBÉ ÈKÓ ÌMÒ ÈDÁ ÈDÈ NI
Èkó ìmò ìjìnlè nípa àyíiká wa: Ó jé ònà tí a lè ba kégbé láti mo èdè si àti ìsesí tàbí ìwùwàsí wa nípa èdè ní Àyííká tàbí kíkégbépò.
Èkó ìmò ìjìnlè èdè ti ìwé ìtàn: Ìmò ìjìnlè èdè ti ìwé ìtàn jé kíko nípa bí èdè ti lè yípadà tàbí se ìyípadà rè pèlú àjosepò àwon èdè.
ÈKÓ ÌMÒ ÌJÌNLÈ ÈDÈ ÀTI ÀSÀ: Èyí ni láti mo ìbásepò tí ó wà láaárín àsà àti èdè.
ÈKÓ ÌMÒ ÌJÌNLÈ ÈDÈ ÀTI LÍLÓÒ WON: Èyí ni láti mò bí ìmò èdè àti lílóò won se le è mù ìtumò dání.
Lákòótán, èkó ìmò èdá èdè kó pín síbì kan àti pé àwon èka rè lókan òjòkan fejú tí a bá yè wón wò fínfín. Ohun tí ó se pàtàkì láti mò nípa ìmò èdá èdè ni mo ti yàn-nà-ná sókè ní sé sè n tè lé.