Health
Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́
ILERA (HEALTH)
Yorùbá bò wón ní ìlera lorò. Ení lówó tí kó ní àlàafíà, onítòhún wá ayé asán nì. Tí a bá ní kí á fi ojú sùnùkùn wo òrò ìlera, tí a sì fé fi ti ènìyàn lásán sòrò lée lórí. A lè so wí pé ìlera jé ètò ìmúláradá, èyí tí ó túmò sí wíwá ní àlàáfíà ènìyàn sùgbón tí a bá ní kí á fi ojú òmòwé tàbí ti olóye wo òrò náà, ó pakaso.
Ìlera jé òrò tí ó fejú láti yàn-nà-ná ni èyí tí ìrònú sì ti wà lóríi rè fún àìmoye odún. Àwon ìlànà à n tèlé méjì kan wà ní àgbékalè fún bí a se le sòrò lé ìlera, ní èyí tíí se “ìlànà ìmò ìsègùn òyìnbó” ati “ìlànà mímó”.
Láti North Amérícà ní ìsègùn òyìnbó, ó jé ìtéwógbà ní ilè North Amérícà ní gbogbo ìgbà. Ní ìbámu pèlú òrò tí a ní láti tún tò tí ó bá dàrú.
Ó fi yé wa wí pé títójú àìsàn àfojúrí kò dára tó fún ìsòro opolo tàbí àwùjo àti kíkàn gbàngbàn nínú titan ìsòro ìlera. Èyí jásí sise àtúpalè ìlera lónà àìtó, bíi àpere: nípàsè àìsàn tàbí iye ènìyàn tí ó kú. Ní ipasè èyí, a lè so pé ìlera túmò sí àìsí àrùn àti kí ara se ojúse tí ó lágbára. Ìgbésè lórí ìdára-eni-lójú; agbára láti jìjàgbara pèlú ìrèwèsì tí ó lè tara ìrònú okàn jáde.
Ní ìlànà pèlú ìlera àwùjo, ìlànà ìsègùn le pe ìlera àwùjo gégé bíi òkan tí ó jé wí pé gbogbo ènìyàn inu rè ní àlàáfíà. Ní ònà mííràn, àtúnse àfiwé le jeyo nínú àwùjo fún ra a rè: àwùjo tí ó ní àlàáfíà jé òkan gbòógì tí gbogbo nnkan bii òrò ajé, òfin, àti béè béè lo kò méhe.
Ní ìbámu pèlú ìlànà mímó; ìlera jeyo láti ara ìtúpalè ìgbìmò káríayé tí n mójú tó ìlera (WHO) tí odún 1947. Ìlànà yìí jé kí èrò àwon onímò ìsègùn gbòòrò sí i, tí ó sì mú èrò ìlera tí ó dántó wá (sùgbón WHO kò lo ìlànà náà). A ka ìtúpalè WHO sí èyí tí ó gbóúnje fégbé. Èyí jeyo Nítorí wí pé kò sí eni tí ó nílò ìwádìí tí ó tako ti àwon onímò ìsègùn. Síso pò mó ènìyàn tí ó wà ní agbègbè ìlànà mímó yóò tún topinpin wíwà dáradára gbogbo ènìyàn ní àpapò.
Ìtúpalè ìlera lè jé gégé bíi ìgbìyànjú oníkálùkù, mòlébí, àkójopò àti àwùjo láti jerí ìsòro-kí-ìsòro tí ó le máa kojúu won. A tún lè so pé ìlera jé “àsìkò tí ènìyàn àti gbogbo nnkan abèmí tí wón jo ní àsepò bá wà títí ayé.
Tí a bá fi ojú sùnùkùn wo àwo ohun tí a ti gbé yèwò nípa ìlera, a ó ri wí pé ìlera se pàtàkì nínú ìgbé ayé gbgbo ènìyàn pátápátá.Bí a se ní ìgbàgbó wí pé tí kò bá sí owó, ènìyàn kàn wá ilé-ayé lásán béè gégé ní ìlera jé eni tí ó bá wá ní ayé tí kò ní àlàáfíà, eni náà ti di òkú.