Ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá
Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Soyemi, Oluyinka Benjamin
SOYEMI OLUYINKA BENJAMIN
ÈKÓ NÍPA ÀWÙJO-ÈDÁ
Èkó nípa àwùjo-èdá jé èkó kan pàtàkì tí kò se é fowó ró séyìn. Kò sí èdá alààyè tó dá wà láì ní Olùbátan tàbí alájogbé. Orísirísi ènìyàn ló parapò di àwùjo-bàbá, ìyá, ará, òré, olùbátan ati béè béè lo. Bí ìyá se ń bí omo, tí bàbá ń wo omo àti bí òré àti ojúlùmò se ń báni gbé, béè ni ìbá gbépò èdá n gbòòrò si. Gbogbo àwon wònyí náà ló parapò di àwùjo-èdá. Àti èni tí a bá tan, àti eni tí a kò tan mó, gbogbo wa náà la parapò di àwùjo-èdá. Ní ilè Yorùbá ati níbi gbogbo ti èdá ènìyàn ń gbé, ìbágbépò èdá se pàtàkì púpò. Bí enìkan bá ní òun ò bá enikéni gbé, tí kò bá gbé nígbó, yóó wábi gbàlo. Sùgbón, àwa ènìyàn lápapò mo ìwúlò ìbágbépò. Orísirísi ànfàní ni ó wà nínú ìbágbépò èdá. Bí òpò ènìyàn bá n gbé papò, ó rorùn lati jo parapò dojú ko ogun tàbí òté tí ó bá fé wá láti ibikíbi. Yorùbá bò wón ní àjòjì owó kan ò gbérù dórí. Béè gégé ló se rí fún àwùjo-èdá. Gbígbé papò yìí máa ń mú ìdádúró láì sí ìbèrù dání nítorí bí òsùsù owò se le láti sé, béè ni àwùjo tó fohùn sòkan. Èyí jé oun pàtàkì lára ànfàní tó wa nínú ìsòkan nínú àwùjo-èdá. Nídà kejì, bí òrò àwùjo-èdá ba jé kónkó-jabele, èté àti wàhálà ni ojú omo ènìyàn yóó máa rí. Nítorí náà, ó dára kí ìsòkan joba ni àwujo-èdá. Ìdàgbàsókè tí ó máa ń wà nínú àwùjo kò sèyìn ìfowósowópò bí àti ránmú un gángan ò ti sèyìn èékánná. Ó ye kí á mò pé nítorí ìdàgbàsókè ni èdá fi ń gbé papò. Bí igi kan ò se lè dágbó se, béè náà ni enìkan ò lè dálùúgbé. Òpòlopò ènìyàn ló máa ń dá Ogbón jo fún ìdàgbàsókè ìlú. Bí Ogbón kan kò bá parí isé, Ogbón mìíràn yóó gbè é léyìn. Níbi tí orísirísi ogbón bá ti parapò, ìlosíwájú kò ní jìnnà si irú agbègbè béè. Gbogbo àwon nnkan wònyí jé ànfàní tó wà ní àwùjo-èdá tí kò sì se é fi sílè láì ménu bà. Nínú èkó nípa àwùjo-èdá, a tún máa ń sòrò nípa ìsòro tó ń kojú ìbágbépò èdá. Kò se é se kó máa sì wàhálà láwùjo ènìyàn. A kò lè ronú lónà kan soso, nítorí náà, ìjà àti asò máa ń jé àwon nnkan tí a kò lè sàì má rì í níbi ti àwon ènìyàn bá ń gbé. Wàhálà máa ń fa òtè, òtè ń di ogun, ogun sì ń fa ikú àti fífi dúkàá sòfò. Àwon nnkan wònyí jé ara àwon ìsòro tó n kojú àwùjo-èdá. Kò sí bí ìlú tàbí orílè-èdè kan kò se ní ní òkan nínú àwon àwon ìsòro wònyí. Sùgbón, a gbódò mò wí pé awon ànfàní àti awon ìsòro wònyí ti wà láti ìgbà pípé wá. Tí a bá wo àwon ìtàn àtijo gbogbo, a ó ri pé gbogbo àwon nnkan wònyí kò jé tuntun. Ogbón omo ènìyàn ni ó fi se okò orí-ìle, ti orí-omi àti ti òfúrifú fún ìrìnkèrindò tí ó rorùn. Àwùjo-èdá ti se àwon nnkan dáradára báyìí náà ni wón ń se àwon ohun tí ó lè pa ènìyàn lára. Fún àpeere, ìbon àti àdó-olóró. Àwon ohun ìjà wònyí ni wón lò ní ogun àgbájé kìnní tí o wáyé ní Odun 1914 sí 1918 àti ti èkej