Informatics (Ifitonileti)
Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Informatics (Ifitonileti)
OWOLABANI JAMES AHISU ati AKINDIPE OLUWABUNMI TOPE
Ètò Gírámà
Ìfáàrà
“Ní àtètèkóse ni òrò wà …” (Jóònù 1:1)
Kì í se ohun tó dájú ni pé akékòó èdè kòòkan yóò jiyàn pé òrò ni wúnrèn ìpìlè fún ìtúpalè nínú àwon gírámà. A lè yígbà yígbà kí a wádìí lítítésò fún àríyànjiyàn lórí mófíìmù, sùgbón léyìn gbogbo atótónu yìí, kí ni a rí? Sé ó léni tó n so mófíìmù tó dáwà tí won kìí sìí se òrò fúnra won? kí ni ó wà nínú òrò–síso tó ní ìtumò? Kí ni àwon ìdánudúró fún gbólóhùn? Òrò ni àárín, inú, àti àwon ìbèrè òrò.àjòmó ìbèrè, kódà fóníìmù pèlú kò lè dá dúró tí kò bá ti lè làdì sí ìtumò nínú òrò. Ní àtètèkóse ni òrò wà. Ó wà níbè láti dá ayé ofò sílè, láti mo àti láti tún òrò–síso mo, láti fikún, láti yo kúrò àti láti mú ye ní orísìírísi ònà.
E jé kí á padà kúrò ní àníjé ìmó wa lo sí ajúwè nínú gírámà; ètò rè ìlànà ìfojú- ààtò-wò àti àlàyé rè. Fífi ojú gbogbo ayé wo gírámà, a máa se àpèjúwe ètò gírámà pèlú àwon òrò, ní ìbèrè, ní pàtàkì pèlú èdè Gèésì àti Yorùbá kí a sì fi àpéjo àwon ènìyàn tí n gbó òrò sílè láti dásí ìfihàn nípa títeríba fún èrò ìlànà tí a fi lélè fún ìtúpalè ní èdè tirè, èdè ènìyàn mìíran. Àkíyèsí ni pé tí èdè Gèésì àti Yorùbá, àwon èdè tí kò tàn móra won tó gbilè, ni a lè tún se àtúnse rè sí àwon òfin tí a ti gbìmò won níbí, ó se é se kí àwon nnkan tí à n rò jé òtító, kí ó sì sisé fún èdè mìíràn títí dé àwon àbùdá àìròtélè àwon èdè kan. Bí èfè yen kò bá mú ìbàjé wá, à á se àtúnwí àbá kan náà pèlú èyí: àwon tí won kò gba èyí gbódò mò nínú won pé nígbà tí wón bá n se ìtúpalè àwon èdè won ni àwon èrò yìí, èrò yìí ni a máa se atótónu wa tí ó kún lórí rè fún àpeere èdè Yorùbá, ‘Hausa’, èdè Gèésì, èdè ‘Ibibio’… àwon èdè tí a kójo pèlú ìyàtò ni wón ní ìbásepò kankan nítorí pé wón jé èdè ènìyàn. Síbèsíbè, tí a bá fi owó gírámà kan náà mú won, à n so pé wón ní ìjora, bí okùnrin elédè Gèésì se jo okùnrin elédè Yorùbá kan, tí ìyàtò won sì jé ti àwò won. Ìyókù orí yìí yóò mú wa wà ní ìmúra sílè láti rí ìdí tí àwon onímò èdè fi n kóòdù àwon ìtúpalè won bí wón bí wón se n se.
2.1 ORO Fífún àwon òrò wònyí lédè Gèésì:
1. Okùnrin, ìwé, kálámù, òòtè, ife, Olè, síbí, tábìlì, òsùká, téèpù,
eni tó rí so Gèésì kò ni ní wàhálà nípa sísèdá:
2. Àwon okùnrin , àwon ìwé, àwon kálámù, àwon òòtè, àwon ife, Àwon síbí, àwon tábìlì, àwon òsùká, àwon téèpù.
Ó ti pinu ní okàn rè láti mo ìsodorúko àwon òrò náà àti àwon òrò orúko (Latin: nomen ‘name’) ni a lè so di òpò ----- àwon àpeere pò nípa àwon nnkan ti a so lórúko. Nípa ti iye ìtèsí rè, a lè fi àwon òrò mìíràn bí i kan tàbí náà kún òkòòkan àwon òrò náà. Yíyéni láì sàlàyé tóbé è jùbé è lo gírámà rè ni gbìmò tíórì kan pé kí gbogbo àwon òrò orúko gba àwon átíkù kan tàbí náà. Lára àwon ìdájó rè ni ó jé pé átíkù wo ni ó síwájú tí ó sì tèlé àwon òrò pàtàkì nínú ìwé tí à n kà lówó láti túmò rè, sùgbón kò sí ohun tí ó dá yàtò nípa:
3. ife náà ~ ife kan
síbí náà ~ síbí kan
Ohùn kan tó tún dìjú ni pé, nígbà tí a bá mú ìkan lára àwon átíkù wònyí, ní dandan òkan lára àwon tó lè dá dúró tí a pín sí abé òrò orúko gbódò tèle, sùgbón kì í se dandan kí síso òrò jé òotó! Ohunkóhun tó bá selè, à n tè síwájú láti so pé bí a bá ní òrò kan, ohun mìíràn, tí ó wá láti ìpín mìíràn, lè tèle tàbí kí ó máa tèle, nínú síntáàsì, a máa n lo ònà mìíràn làti so pé:
4. X: Y; + {__ (Z)}
Òrò kan tó jé X ni a pín gégé bí Y àti pé ó lè jeyo pèlú àwon òrò Z, Z jé òrò kan tí ó lè wà tàbí kí ó má wà nílé nígbà náà. Tí a bá n fojú isé onà wò ó òrò kan tó jé X ni ìpín onítumò àdámò (ìsòrí òrò) Y ní abgègbè tó saajú òròmìíràn Z, wíwá níbè Z jé wòfún. Àkosílè afòyemò tí òkè yìí ni à n pè ní àpíntúnpín sí ìsòrí tó múná dóko ni a jíròrò lè lórí nínú Yusuf (1997). Tí a bá padà sí àwon àpeere (1,2) ti òkè, eni tí n sòrò lórí bí a se lè mo àwon tí ó dá dúró yìí to jé òrò oruko tí o lè wà ní ipò tó se kóko; olùwà àti àbò. Lára àwon ìmò rè nípa àwon òrò wònyí ni pé a lè fún wón ni àwon ipa kan láti kó; tí a bá ní ká wò ó kí ni ìwúlò won tí won kò bá kó ipa kankan ní àyíká gbólóhùn tàbí ofò won. Fún àpeere, olè kan jé òsèré, olùkópa tí ó bá kópa níhìnìn tàbí òhún láti mú àpíyadà wá. Nígbà tí ó bá n serè, a mò pé ó lè jalè. Kódà kì í se olè tí a kò bá mò ó sí eni tó jí nnkan kan nítorí nínú gbólóhùn bí i.
5. Olè náà jí kálámù
Òrò náà tó jé ‘ole’ so ohun tó pò. Ó jé òrò tó mú náà, tóje átíkù, ó lè yàtò fún oye àwon olè àti pé ó je ÒSÈRÉ nínú àyè ofò tó lè mú ìyípadà bá ìfarasin kálámù náà. Rántí pé òrò náà ‘kálámù’ wà ní ìsòrí yìí náà pèlú; ó máa gba átíkù náà/kan tí a lè gbékalè ní òpò (àwon kálámù) àti pé a fé fà á yo, gégé bí àwon ojúgbà rè, wí pé ó jé olùkópa ní àyíká gbólóhùn náà sùgbón ní báyìí ó n kó ipa ohun tí wón jí, ipa náà ni a máa pè ni ÀKÓSO. Opolo wa so fún wa pé kálámù kan lè jé ohun ÈLÒ fún ìbánisòrò. Àwon ipa náà, tí àwon álífábétì nlá dúró fún ni à n pè ní Àwon ipa asekókó, a lè gé e kúrú sí ‘Theta – roles’, tí wón máa n kò gégé bí i ‘Ø roles’, bí ìtèsíwájú bá se n bá ìtúpale wa. Ko lè sí ohun ìtókasí tó dúró, àwon olùkópa kan tí a lè tòka sí, nawó sí, dárúko, sòrò nípa, tí kò ní gba ‘Ø role’ kan. Àwon àjoni tí a sábà náa n rí ‘Ø roles’ je OLÙSE, OLÙFARAGBA, (nígbà mìíràn tí a máà n pè ni Àkóso), ÒPIN àti ÈLÒ. Òpòlopò àwon onímò lìngúísíìkì mo àwon mìíràn dájú.
Àwon àbùbá àdámó òrò wà tí a lè tóka sí báyìí. Àwon àbùdá mìíràn máa hàn kedere tí a bá gbé èdè tó yàtò sí èyí tí a ti mò télè yèwò. Nítòótó, a máa so pé ìwúlò wò ni ó wà nínú kí a máa sòrò nípa àwon ohun tí a kò rí nínú èdè wa! Ìkìlò: À n sòrò nípa àwon àbùdá tó wà nínú èdè ènìyàn, kì í kan n se nínú èdè Gèésì tàbí èdè Yorùbá. Rántí ohun tí a rò nípa Gírámà Àgbáyé, Èdè Gèésì, èdè Ìgbò, èdè ‘Eskimo’, èdè ‘Japan’…….. jé díè lará èdè ènìyàn tí wón sì ní àwon ìyàtò won, nínú ohun tó se kókó báyìí, fífún àwon òrò asèdá òrò asèdá bí i ÒPÒ ‘Ø role’, àwon ipò onítumò gírámà, abbl.
E jé kí á fi àbùdá kan kún àwon àpeere wa. Àwon òrò náà ni a lè yí padà. Ní béè à á ní:
6a. Okùnrin alágbára kan
b. Ògbójú olè kan
d. Igi oaku kan
e. Téèpù mímógaara kan
e. Ife kan tó kún fún kofí
f. Òsùká kan fún ìbòsè aré bóòlù àfesègbá
Àwon wònyí jé àwon èpón tó jè wí pé bí a bá yo wón kúrò ìtumò àwon òrò náa kò ní dínkù (ìsomó). Àwon àkámó tí a lò nínú àpíntínpín sí ìsòrí tó múná dóko àti àwon tí a fihàn ní orí kìíní, ni a lè lò báyìí, bí i (T).
7a. ife kan ([tó kún] fún kofí)
b. téèpù (mímógaara) kan
c. Okùnrin (alágbára) kan.
Àwon ohun tí a fi sínú àkámó ni à n pè ní àwon ìsomó, won kò ní apíntúnpín sí ìsòrí, won kì í se dandan, wón je èpón –on wòfún. Nígbà tí àwon wònyí tún wúlò níbò mìíràn, a fe yán an pé kìí se gbogbo àwon èpón ló jé wòfún. Kódà nígbà tí won kò bá ní ìtumò àdámò wón wúlò. Fún àpeere, oba tàbí olorì kò níyì bí oba tí won kò bá ní ìjoba tiwon. ní béè a ní:
8a. Oba tí Èkó
b. òbí ti Agbor
d. Oba àwon Júù
Kódà Oba bìnrin ‘Elibabeth’ tí ó tó láti se ìtóka ni a mò pé ó ní agbára lórí ilè Gèésì. Àkíyèsí pé láti so pé Oba bìnrin náà, láà jé pé ènìyàn n gbé nílè Gèésì tàbí tí iyè rè so pèlú oríle – èdè náà, máà sàì nítumò. Orúko àbíso lè tó láti mo àwon orí oyè, sùgbón ìjoba won tí se pàtàkì jù, èpón wòfun. Àwon èpón ni à n pè ní Àwon Àfikún. Ní kúkúrú, àwon èpón PP ti oba àti oba àti oba je wúnrèn tí a ní lò.
2.2 Àkópò kúkúrú kan
Àwon òrò, tí a fihàn gégé bí i àwon òrò orúko, gba àwon nnkan mìíràn móra dandan, ‘DET’, Àwon ipa asekókó, ÌSODÒPÒ, àwon kan– npá àti wòfún (ákámó), àwon Àfikún àti àwon Ìsomó bákan náà, àti àwon mìíràn tí a kò ménu bà. Àwon àbùdá àdámò ti olùso èdè rè gbódò mò ni àwon wònyí. Ó jé dandan pé ó mo òpòlopò, lára èyí tí a máa so tó bá yá ní ìfìwàwèdá. A fé je kí àwon akékòó mò pé àwon nnkan wònyí jé àìkó, lára àwon akówòó rìn UG nínú àká – òrò náà (atúmò èdè tí iyè náà). A ménu bà á pé àwon nnkan wònyí kìí hànde bákan náà, sùgbón ó lè gbón fara sin sínú àwon kóòdù mofólójì nínú òrò náà, ní àwon àyíká tí a kò funra sí.
2.3 Òrò náà (2)
Àwon àkójopò àwon òrò tó yàtò sí ti àkókó máa fún wa ni àwon nnkan. E je kí a mu àwon òrò tó n so nípa àwon òrò orúko.
1. talk, kill, endure, wait, eat, drink, write, see
fún àwon elédè Gèésì, àwon òrò wònyí jé òrò ìse (Latin: verbum ‘Word’), won le fi àsìkò ìsèlè hàn nípa gbígba àwon àfòmó:
2. talk: talks, talked, talking,
kill: kills, killed, killing.
X X-s X-ed X-ing.
Àwon gégé bí àwon òrò orúko lè gba àwon àbò àwon kan wòfún ni (àwon òrò ise agbàbò) nígbà mìíràn ó jé wòfún nígbà tí wón bá jé aláìgbàbò sùgbón tí won bá gbà àwon àbò tan, tàbí kí won máà gba àwon ìsomó kankan.
3. eat (NP)
kill (NP)
drink (NP)
[+ liquid].
Àwon ìsomó máa n borí àwon àpólà (tí ó lè je eyo òrò kan soso) sí àwon àpólà orúkò. Níbí ni a se àpèjúwe ránpé nípa àwon Àfikún òrò ìse sí.
4a: eat ([NP an unripe mango])
b. destroy [NP the termitarium]
c. said [s. that [s the NBA examination is
canceled]]
d. put [x [NP salt] [pp in the soap]]
e. saw [NP Móremí].
Àwon òrò ìse aláìgbàbò ni a máa fihàn nísàlè, pélù àwon ìsomó.
5a Jòkó sórí ení
b. Sùn síjòkó èyìn òkò
d. La àlá
e. Kú.
Nígbà tí àwon yìí kò gba àwon àfikún, wón lè, nípa ìgba àkànse gba àwon àbò - àwon àbò àkànse tí a so mo won tàbí tí a sèdá láti ara won. Wón fejó Èsù so nínú Bíbélì pé ó n gba Éfà níyànjú láti ma bèrù nípa jíje èso èèwò, tó wí pé, “Èyin kò ní kú kan”. Èsù kò nílò àti yí òrò ìse aláìgbàbò sí agbàbò
Nitóri pé wón n sòrò nípa àwon òrò orúko wón fi àwon nnkan pamó lórí àwon irú òrò orúko (kódà yíyípadà) ní àwon èdè kan. Èdè Gèésì kìí se àpeere tó dára nípa bí òrò ìse se lè yí òrò roúko tí a bá wèyìn, ipa asekókó ÒSÈRÉ, ÀKÓSO, ÈLÒ, abbl wá tààrà tàbí àìsetààrà láti ara òrò ìse. Fún àpeere alè máà ri sùgbón a mò pé N kan náà (nítòótó NP) ni ó n kú nínú:
6. Olú pa olè náà
Olè náà ni olú pa Àti pé kò sí àníàní, NP kan náà tó fa ikú bó tilè jé pé ìtò gégé ní àwon olùkópa nínú gbólóhùn méjèèjì wà. Fún béè Olú ni ÒSÈRÉ nínú gbólóhùn méjèèjì nígbà tí Olè náà jé Àkóso nínú méjèèjì bákan náà. A lè sòrò nípa àwon òwó òrò mìíràn, tó yàtò sí Àwon òrò orúko àti àwon òrò ìse, sùgbón e jé kí á padá séyìn láti wo àwon ìjíròrò wa fún ìbáramu. À n so pé òrò kòòkan, bó jé òrò orúko tàbí òrò ìse, máa n wá pèlú àwon nnkan. Nínú ìbásepò won, àwon òrò náà n sisé lórí ara won to fi jé pé àwon òwò kan a gbà àwon mìíràn yóò sì fún won ní àwon àbùdá kan. Òrò orúko náà, tó máa n jé olùkópa, kìí se ÒSÈRÉ tàbí ÀKÓSO tí òrò kò bá fún won ní irú ipa béè. Nínú òrò – èdè tí ayé (tí a gbé wonú gírámà) òrò ìse tó n darí àbò APOR rè fún ìdí èyí, ó n fún ní isé (ní báyìí, Ø role nìkan, àmó ó lè se àyànse àwon àwòmó mìíràn).
Gégé bí olùso èdè se nu ìmò nípa àwon nnkan wònyí láìkó tí ó sì je pé dandan ni ó n tèlé àwon ofin yìí, se a kò lè so pé àwon ogbón ètò yìí jé abínibí gégé bí mímí se je?
2.4 Àwon ibi gíga
Ìwòn mìíran nì a ti menu bà télè, nípa òrò náà, ohun náà ní pé kìí jeyo ní dídáwà. Olè di Olè náà, ògbójú Olè náà, ògbójú alágbára Olè náà pèlú ìwo, abbl. Àwon àlèpò òrò náà sí àwon òwó tí ó tóbi pèlú ìrànlówó àwon ohun tí a pè ní àwon àpólà. Nítorí pé àárín òrò, òrò gangan tí a bá túnse nì yóò dúró fún odidi àpólà, a máa n pé irú won ni Ori. Ni a se máa rí i, òrò orúko ní ó máa n jé orí fún Apólà orúko (APOR), òrò ìse fún Àpólà ìse (APIS), òrò àpèjúwe fún Àpólà àpèjúwe (APAJ)….,X tàbí Y tún àpólà X (XP) àti àpólà Y (YP) bákan náà. Léèkan sí, ká wò ó pé olùso èka –èdè rè mo púpò nípa rè. Yorùbá máa mò mò pé omo ‘child’ ni a lè tó àwon òrò èpón mó bi i omo kékeré ‘small child’, omo baba Ìbàdàn ‘the child of the man from Ìbàdàn’ tàbí omo náà “the child” kò di dandan, àti pé kódà, won kò tí ì kò ní àwon àtòpò yìí rí. Àti wí pé opolo tí olùso èka–èdè yìí n lo ni a fé gbéyèwò nínú gírámà, Akitiyan láti mo ohun tí ó mò láì kó. Se kò pani lérìn-ín, olùso èka – èdè, tàbí omodé kan n kó àwon orímò èdá–èdè kò ní ìtumò sùgbón òótó ni.
A se àfiikún àwon àpólà tí a kó tí olùso èka–èdè lè lò pé kò ní èkun ó sì peléke. Àwon iní ìhun béè lè kún fún àwon èròjà wòfún tí ó wonú ara won. Sùgbón èyí kéyií tó bá selè, àpólà gbódò ní orí, títèlé àwon ohun tí òfin níní orí gbà, tí a pè ní ‘endocentricity requiremrnt’. Nítorí béètí a bá ní òrò kan W, ó gbódò di W max tí a túpalè ní síntáàsì gégé bí i WP (for W-Phrase) tàbí W” (W- double prime (=bar)).