Átọ́mù
Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Atomu ni a mo si ohun to kere julo fun awon apilese (element). Bo tile je pe atomu ni ede Griki tumosi eyi ti ko se fo si wewe, imo atomu nisinyi ni pe awon ohun abeatomu miran tun wa:
Akowa ati alaigbara ni won po ti won kun inu inuikun atomu (atomic nucleus) a si n pe won ni abikun (nucleons). Nigbati atanna si parapo da ìsú atanna to yipo inuikun.
O se se ki atomu o yato nipa iye awon ohun abeatomu ti won ni. Atomu ti won ni apilese kanna ni iye akowa kanna (ti a mo si nomba atomu). Fun apilese kan pato, iye alaigbara yato, eyi si ni n so bi olojukanna (isotope) apilese na yio se ri. Atomu ko ni agbara ina kankan ti iye akowa ati atanna won ba dogba. Atanna ti won jinna julo si inuikun atomu se gbe lo si odo atomu miran to wa ni tosi won tabi ki won o je pin larin awon atomu o hun. Bayi ni awon atomu se n sopo lati di ẹyọ (molecule). Fun apere eyo kan omi je akopapo atomu meji hydrogen ati atomu kan oxygen. Atomu ti atanna won ku die kato tabi to po ju bose ye lo ni an pe ni ioni. Ona miran ti iye akowa ati alaigbara fi le yipada ninu inuikun atomu ni yiyo inuikun (nuclear fussion) tabi fífọ́ inuikun (nuclear fission).
Atomu je ipilese ti ẹ̀kọ́ egbò (chemistry) duro le lori, be ni won si kopamo (conserve) ninu adapo elegbo (chemical reaction).
[s'àtúnṣe] Atomu ati eyo
Fun awon elefufu (gas) ati onisisan (liquid) ati onilile (solid) eleyo (molecular) (fun apere omi ati suga), eyo je ipin to kere julo ohun ti o ni idamo elegbo.
i